Skip to main content

Posts

AWE GBOLOHUN (JSS)

 AWE GBOLOHUN   AWE GBOLOHUN ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa n se . ona meji Pataki ni awe gbolohun pin si . Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe, Olori awe gbolohun maa n da duro, yoo si ni itumo, o si maa n sise gbolohun abode. Apeere   1) Ola ti sun                2) Mo n bo   Awe gbolohun afarahe tabi afibo : eyi ni gbolohun ti ko le da duro ko si fun wa ni itumo, o maa darale olori gbolohun ni, o si maa n wonpo ninu gbolohun olopo oro ise ( onibo )   Lara awon atoka gbolohun afarahe ni : ti, pe, ki, iba, bi, boya, tabi ati bee bee lo. Awe gbolohun le wa ni   ibeere, aarin tabi ipari gbolohun. Isori meta ni a le pin si. Awon si ni : 1.     ASODORUKO 2.     ASAPEJUWE 3.     ASAPONLE AWE GBOLOHUN ASODORUKO : eyi ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko nipa lilo oro atoka   “PE” Apeere   : ...

ISE AGBE ATI ISE ILU (JSS1)

  ISE AGBE Ise agbe je ise ti o gbajumo ju lo ni ile Yoruba.Ise agbe se Pataki nitori awon ni won n pese ounje fun ara ilu. Awon agbe ni won n gbin ere oko bii paki, ere/ewa, isu,agbado,ata, efo ewedu,epa ati bee bee lo.A le pin agbe si orisi meji . (i)              Agbe Alaroje (small scale faming) :Agbe alaroje ni awon agbe kekeke ti won n da oko etile fun jije ara won. (ii)            Agbe Aldaa-nla (large scale farming) :Agbe Alada-nla ni awon ti won n dako egan,ti won n fi ise agbe sise se. ISE ILU LILU Ise abinibi ni ise ilu lilu je fun awon iran ayan.kaakiri ile Yoruba ni ise yii gbajumo.Ibi ti won ti n se nnkan eye,odun ibile,ni won ti n lulu.Amuludun ni awon onilu je.Ibi ti won ba ti n lu ilu,orin ati ijo kii gbeyin nibe.Ise idile ni ise ayan je sugbon won tun maa koi se ilu naa. A le pin ilu si meji gege bi lilo won.Awon ni : 1)    Ilu fun ...

ATUNYEWO OGE SISE SS

Atunyewo oge sise    Sise ara loso ni oge sise je . Ajo ewa ni oge sise je.oge sise bere lati irun ori titi de kokose ati eekanna . Isori-isori ni awon itoju ara, O bere lati itoju irun ori, tiroo lile, ila kiko, oju yiya, eyin pipa, ete kikun, aso wiwo, afa finfin. Lalii lile, ila kiko, eti lilu, ileke wiwo  ati bee bee o Okan ninu awon ona oge sise ni Aso wiwo. A le pin wiwo si ona meta : 1.      Aso ise 2.      Aso iwole/awogbele 3.      Aso amurode. Awon Yoruba maa n lo aso ni ibamu pelu asiko, bee si ni bi obinrin ti ni aso tire naa ni okunrin ni tire pelu. Awon  aso obinrin ni aye atijo ni: 1.       Aso awon obinrin je eyi ti ko le di won lowo lenu ise won bii Iro, ewu ati awotele bii agbko, tobi tabi yeri. 2.      Awo iwole won yato pupo si ti oke yii afi pe won le we gele ti ko fe bee lowo lori. 3.      Aso imurode...

: IWA OMOLUABI ATI ISORO TO N KOJU RE JSS

  :  IWA OMOLUABI ATI ISORO TO N KOJU RE. Ni ile Yoruba iyi ni lati pe enikeni ni omoluabi. Omoluabi ni eni ti iwa re dara pupo, to n hu iwa rere ati iwa to ye ninu ile, ijo, egbe ati laaarin ilu. Owo-nini, ogbon-inu tabi gbajumo ko so ni di omoluabi. Yoruba won ni iwa rere leso eniyan. AWON IWA TO N MU NI JE OMOLUABI OOTO SISO : omoluabi gbodo je olododo to se e fi okan tan ni gbogbo igba, omoluabi ko je huwa abosi, ireje, puro tabi gba ohun olohun mo ti. IBOWO FUN AGBA: omoluabi ni eni to ni owo ati iteriba fun agbalagba ati gbogbo awon ti o ju u lo. Omoluabi eniyan maa n teriba fun aba tabi ogbon agba, bee ni k I lodi si imoran won. Ni ile Yoruba , a n bowo fun awon eniyan ti won ba wa ni ipo, bii Oba, Ijoye ati bee bee lo. IWAPELE ATI SUURU : omoluabi gbodo je eni ti ki I binu odi, bee ni o gbodo je eni to ni suuru, tI oro enu re maa n je iwuri ati iyanilori. O je eni ti o ma se ohun gbogbo pelu irele.   IKINI : ibi ikini ni a ti n mo ojulowo eniyan. Omo...

AWON EYA YORUBA JSS 1

AWON EYA YORUBA   Awon eya Yoruba ni awon ti won gba Oduduwa gege bi babanla won, ti won si n so ede Yoruba gege bi ede abinibi AWON EYA YORUBA ILU ABE WON OUNJE WON 1.    OYO OYO, IBADAN, OGBOMOSO, IWO, EJIGBO, IKOYI-ILE   EKO YANGAN, AMALA ATI GBEGIRI 2.    EGBA ABEOKUTA, OWU, IBEREKODO GBEGURA, OKE-ONA AMALA FUNFUN 3.    IFE ILE-IFE, IFETEDO, OKE-IGBO, AMALA OGEDE 4.    IJESA ILESA, ESA-OKE, IJEBU-IJESA IYAN, AKARA 5.    EKITI ADO, IJERO, IMESI-OKE IYAN & EGUSI 6.    ONDO ONDO, ILE-OLUJI, IDANRE IYAN 7.    ILORIN ILORIN , LADUBA, AFON TUWO 8.    EKO ISALE-EKO, OSODI, AGEGE E...

ORAN ATI IDAJO TI O TO

  ORAN ATI IDAJO TI O TO Awon Yoruba ni igbagbo ninu idajo ododo, won ki i si n fi ejo se egbe. Gbogbo oran ni o ni ijiya to to labe isakoso ijoba laye ojoun, amo bi o tile je pe eto ofin fi ese mule ni aye awon baba nla wa, sibe nwon igba to je pe ko si eto bi-mi-ki-bi-e tabi eko ofin iru ti ode oni, opolopo awon ti ko mowo mese maa saba jiya ese ti elomiran da. Eyi lo mu ki awon babanla wa maa   pe “ Ori yeye ni mogun, ipin aise lo po ni be.” Eyi ni ate apeere oran ati ijiya fun okookan ni aye atijo. ORAN IJIYA TABI IDAJO Ipaniyan Bibe ori iodaran si Mogun Ifadiya Mimu odaran sanwo itanran bi o ba onile, bi o ba je alejo, sisan owo itanran ati lile kuro ni ilu pelu Jibiti lilu Dida owo pada ati sisan owo itanran. bi o ba je alejo, sisan owo itanran ati lile kuro ni ilu pelu Gbigba emi ara eni lainide Gbigba emi ara eni bi akin Sisin laisi ayey...

AGBEYEWO ALO

  ALO APAMO ATI APAGBE  SSS  ALO                                                        Alo tumo si ohun ti a lo, ki a lo nnkan tumo si ki a lo ona alumokoroyi, eyi ni pe a la oro mole lona taara, dipo bee, a pe e so ni. Pipe ni a ma pe alo, iro si ni je alo. Ale ni a ma pa alo nigba ti gbogbo ise oojo ba ti dopin. Awon Yoruba ka eni ti o ba pa alo ni osan gege bi alaarooye ati ole afajo. Orisi alo meji lo wa, awon wonyii ni alo apamo ati alo apagbe (alo onitan). ALO APAMO : okan lara ere osupa ni alo apamo je nitori leyin ise oojo ni a maa n pa alo. Omode lo ni alo sugbon awon agba ni won maa n paa fun won nitori aditu ni alo. O gba arojinle gidi lati tumo re. ko si ofin ti o de ojo ori , eya, ako ...