ALO APAMO ATI APAGBE SSS
ALO
Alo tumo si ohun ti a lo, ki a lo
nnkan tumo si ki a lo ona alumokoroyi, eyi ni pe a la oro mole lona taara, dipo
bee, a pe e so ni. Pipe ni a ma pe alo, iro si ni je alo. Ale ni a ma pa alo
nigba ti gbogbo ise oojo ba ti dopin. Awon Yoruba ka eni ti o ba pa alo ni osan
gege bi alaarooye ati ole afajo.
Orisi alo meji lo wa, awon wonyii ni
alo apamo ati alo apagbe (alo onitan).
ALO APAMO : okan lara ere osupa ni
alo apamo je nitori leyin ise oojo ni a maa n pa alo. Omode lo ni alo sugbon
awon agba ni won maa n paa fun won nitori aditu ni alo. O gba arojinle gidi
lati tumo re. ko si ofin ti o de ojo ori , eya, ako tabi abo ati ipo akopa. Bee
ni ki i ni ibudo pato. Ibi ti awon omo baa parapo si naa ni a ti n pa. Nigba ti
awon obi ba n se ounje lowo, ti won si fe ki won sun ki ounje to jinna tabi
lati dekun ere egele ni won maa ni pa alo.
Alarogun ati alarojinle ni awon Yoruba. Eyi ni
won fi n gbe alo apamo kale. Bi won ba se akiyesi irisi, iseda ati iwa nnkan
kan, won le fi gbe alo apamo kale. Alo apamo ni o maa siwaju alo apagbe(alo
onitan)
Ibeere ati idahun ni alo apamo, Oluso yoo
beere ibeere, olugbo yoo si dahun.
Ihun bere alo bayii : Oluso : Aalo
oo, Olugbo : Aalo.
APEERE ALO APAMO
1.
Okun n ho yeeye, Osa n ho yaaya, omo buruku
tori bo o. kinni oo ? (omo orogun)
2.
A ni ki o ya orun, oya orun, A ni ki
o ya ina, O ya ina, A ni ki o wa we o ni iku de o. kinni oo ( IYO)
3.
Winni winni aso orun, Eni hun un ko mo-on. Eni to ra a ko mo-on. Kinni oo (
OYUN)
4.
Gbogbo igi lo wowe, Sapata o wowe.
Kinni (igi-ope)
5.
Mo sumi barakata. Mo fewe feregede bo
o. kini oo. ( ile ati Oju Orun)
ALO ONITAN : Eyi ni o maa tele alo
apamo ni opolopo igba. Gege bi oruko re o maa je mo itan ti ki I se ooto sugbon
ti o da le eniyan, eranko, iwin, igi tabi awon ohun alailemi miiran, a si maa ko awon omode ni eko tabi
lati fi idi abajo kan mule. O see se ki
alo onitan ni orin ninu nigba miiran. Awon opitan alo onitan maa saaba jeyo ni
ipo oju-mi-lo-se.
Ibere re ni isorogbesi ti o ma wayw
ni aarin apalo ati agbaloo, iyato si maa
ba isorogbesi lati ibi kan si ekeji.
Apeere : Apalo : Aalo ooo? Olugbo : Aalo
Apalo: Ni ojo kan Olugbo : Ojo kan ni oni je, Ki o je ojo
rere fun wa
Apalo : Ni igba kan Olugbo : Igba kan n lo, Igba kan n bo, Igba
kan ki i tan laye
Apalo : Aalo ooo? Olugbo : Aalo
Apalo: Alo mi da
furugbagboo Olugbo : Ko ma gbe agbo
omo mi lo
Apalo : Alo mi da lori okunrin
kan ati iyawo re
IWULO ALO
1.
Alo maa n je ki omode mo nipa asa
2.
Alo maa n ko awon omode ni eko iwa
omoluabi
3.
O maa mu ife ati irepo wa laaarin
awon omode nipa ipejopo
4.
O maa ko ni bi a ti n ronu jinnle
5.
O maa dani laraya
6.
Alo a maa koni nipa idi abajo
7.
Alo a maa ko ni nipa asa ati ede
Yoruba.
8.
O maa mu awon omode ni akiyesi ohun
ayika
9.
O maa muni raye ronu
.O wulo gege bi ohun
idije tabi ifigagbaga laaarin awon omode.
Comments
Post a Comment