ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA
Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju
tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je.
Ero awon Yoruba ni pe olorun feran
awon orisa wonyi.
Okanlenirinwo ni awon orisa ile
Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo
Obatala ni
awon Yoruba pe ni ALAMORERE. Won
gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu
won
Funfun ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke
funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko
ni iyo ), igbin ati iyan.
Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko
feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja
tabi omi ikasi
Orunmila (
IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa
nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni Eleri-pin
Sango ti a tun
n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin
oyo ri. Won gbagbo pe o ni ogun ati agbara lori ojo, ara ati imona mona. Bi
sango ba n soro ina maa jade ni enu re. awon iyawo re ni OYA, OSUN ati OBA
Awon aworo re ni adosan ati elegun
Sango. Awon olusin re maa n wo aso Osun ti sango feran nigba aye re, won si maa mu Ose Sango lowo. O kunrin
won a maa di irun bi obinrin
Ounje ti sango feran ni amala pelu
obe eweedu, eran agbo, orogbo ati obi. Idi niyi ti won fi n ki bayii : sango oloju orogbo, Eleeke obi.
ESU ni olopaa
tabi onibode. Gbogbo awon orisa ni won si beru re yato si orunmila ti o je ore re. Esu lo maa
ba awon orisa yooku wa ouje, to si n ba won be ebo. Gbogbo ebo to ba gbe lo maa
n fin, Aarun-un si ni ipin tire ninu ebo ti o bar u.
Awon Yoruba n pe Esu ni ase buruku
se-rere. Ibi idarudapo ni o maa wa bakan naa ni o maa fun awon olusin re ni omo
ati owo. Ita gbangba tabi enu odi ilu ni
ojubo esu maa n wa. Ere ti ipako re gun
sobolo seyin ni amin idamo re.
Epo ni ounje
ti Esu feran julo, eewo re si ni adi. Won maa n ki Esu bayi : Esu laalu Ogiri
oko, A so irun waju po mo tipako……
Comments
Post a Comment