:
IWA
OMOLUABI ATI ISORO TO N KOJU RE.
Ni ile
Yoruba iyi ni lati pe enikeni ni omoluabi. Omoluabi ni eni ti iwa re dara pupo,
to n hu iwa rere ati iwa to ye ninu ile, ijo, egbe ati laaarin ilu.
Owo-nini,
ogbon-inu tabi gbajumo ko so ni di omoluabi. Yoruba won ni iwa rere leso
eniyan.
AWON IWA TO
N MU NI JE OMOLUABI
OOTO SISO :
omoluabi gbodo je olododo to se e fi okan tan ni gbogbo igba, omoluabi ko je
huwa abosi, ireje, puro tabi gba ohun olohun mo ti.
IBOWO FUN
AGBA: omoluabi ni eni to ni owo ati iteriba fun agbalagba ati gbogbo awon ti o
ju u lo. Omoluabi eniyan maa n teriba fun aba tabi ogbon agba, bee ni k I lodi
si imoran won. Ni ile Yoruba , a n bowo fun awon eniyan ti won ba wa ni ipo,
bii Oba, Ijoye ati bee bee lo.
IWAPELE ATI
SUURU : omoluabi gbodo je eni ti ki I binu odi, bee ni o gbodo je eni to ni
suuru, tI oro enu re maa n je iwuri ati iyanilori. O je eni ti o ma se ohun
gbogbo pelu irele.
IKINI : ibi
ikini ni a ti n mo ojulowo eniyan. Omoluabi a ma ki ni pelu iyesi ati owo. O mo
ikini ati idahun ti o ye fun igba, akoko, ise ati isele.
AFORITI :
Aforiti tabi ifarada je okan Pataki ninu abuda eda. Omoluabi gbodo ni ifarada,
nitori ko si eda naa ti ko le ni isoro. Bi isoro ba de omoluabi gbodo ni okan lati bori isoro re.
BIBI IRE :
omoluabi yoo mo asiko to ye lati wole sun, omo ti won bi ni ile ire, ti won ko
to gbeko, ko je ba won rin ni oru.
Yoruba ni ijakumo ki I rinde osan, eni a biire kan ki i rin ru.
NINI IFE
ENIKEJI : Ife se Pataki bee ni o se koko, ife ani denu ni a wi . Bi eniyan ba
ni isoro, omoluabi yoo gbiyanju lati ba mu isoro naa kuro tabi din ku, bi a ba
ri eniyan ti o n se lodi si ohun to ye tabi ni ewu, ojuse omoluabi ni lati kilo
fun un.
OHUN RERE :
oro rere gbodo maa tie nu wa jade ni gbogbo igba. Omoluabi gbodo mo oro to to
lati so lawujo
IWA IGBORAN
: Omoluabi ki i se aigboran si oro agba tabi se ori kunkun. Eni ti a ba n bawi
ti o ba warunki, yoo parun lojiji lai ni atunse.
OJUSE
OMOLUABI
1.
OJUSE
OMOLUABI SI OBI
2.
OJUSE
OMOLUABI SI IJOBA/AWUJO
3.
OJUSE
OMOLUABI SI OMONIKEJI
Comments
Post a Comment