Skip to main content

ATUNYEWO OGE SISE SS



Atunyewo oge sise

 

 Sise ara loso ni oge sise je . Ajo ewa ni oge sise je.oge sise bere lati irun ori titi de kokose ati eekanna .

Isori-isori ni awon itoju ara, O bere lati itoju irun ori, tiroo lile, ila kiko, oju yiya, eyin pipa, ete kikun, aso wiwo, afa finfin. Lalii lile, ila kiko, eti lilu, ileke wiwo  ati bee bee o

Okan ninu awon ona oge sise ni Aso wiwo. A le pin wiwo si ona meta :

1.     Aso ise

2.     Aso iwole/awogbele

3.     Aso amurode.

Awon Yoruba maa n lo aso ni ibamu pelu asiko, bee si ni bi obinrin ti ni aso tire naa ni okunrin ni tire pelu. Awon  aso obinrin ni aye atijo ni:

1.      Aso awon obinrin je eyi ti ko le di won lowo lenu ise won bii Iro, ewu ati awotele bii agbko, tobi tabi yeri.

2.     Awo iwole won yato pupo si ti oke yii afi pe won le we gele ti ko fe bee lowo lori.

3.     Aso imurode won po die, awon bii iro ati buba olowo nla, gele olowo nla ati awotele bi agbeko, yeri tabi tobi pelu okun owo. Won a lo  ipele tabi iborun.

4.     Awon obinrin a tun maa fi aro dun aso imurode won ni aye atijo.

Die ninu awon aso ti a fi n da orisiirisii aso imurode won ni laye atijo ni

1.     Sanyan

2.     Etu

3.     Alaari

4.     Petuje

5.     Alagbaa

6.     Agidi

7.     Aran

8.     Kijipa

9.     Teu

10.  Iteko

Orisii irun ti awon obin n di si ori po, die ninu won ni:

1.     kolese

2.     ipako elede

3.     kojusoko

4.     aja-n-losoo

5.     suku

6.     ojo-o-pa-eti

7.     koroba.

 

Awon aso okunrin ni aye atijo ni :

1.     Gber agbe ati gberi ode. Eyi dabi buba, sokoto re a si maa de ojugun duro. Ase ise ni. Orisiirisii ise ni o ni aso tire.

2.     Aso iwole okunrin po sugbon ki I saaba je eyi ti o tobi, ki I si I je aso olowo nla , buba ati sooro

3.     Lara aso amorode okunrin ni dandogo, girike, oyala, agbada, , dansiki, kufutani, ati sulia sapara

4.     Awon sokoto kunrin wa lorisirisii. Awon bii digoo, abida, sooro, atu, kembo. Kamu, ladugb, kafo ati nangudu. Abunju.

5.     Awon okunrin  ni orisiirisii fila, bi apeere, Okiribi, kafo adiro, ikori, labarikada tabi yoti tabi abeti aja, fila onide pereki tabi origin, gobi, ati bee bee lo.

1.     kembe,

2.     sooro,

3.     ladigbo abbl.

Lode oni itesiwaju ti de ba oge sise lawujo Yoruba, ti I o si n peleke si I lojoojumo, oniruuru ni aso reran lokunrin ati lobinrin, sitali irun didi ati kiko ko  lounka, ipara lorisiirisii ti wa, tito lorisiirisii ko gbeyin. Lode oni , owo ti oge sise n gba lo lapo aseso/asoge ki I se kekere.

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)          ...