Skip to main content

Posts

ITOJU ARA ATI AYIKA JSS3 (SECOND TERM)

Eyi ni sise ara eni losoo tabi sise ara loge. Iwa obun ni idakeji imototo. Awon Yoruba korira iwa obun pupo nitori pe o le fa aisan saye eni. ONA TI A LE GBA TOJU ARA ENI 1.    Iwe wiwe 2.   Enu fifo 3.   Irun didi tabi gige 4.   Eekanna gige 5.   Aso fifo 6.   Fifi adi agbon tabi ipara pa ara leyin iwe wiwe 7.    Itoju ounje wa 8.   Lilo ogun to ye : Ilokilo ogun ko dara ONA TI A GBA TOJU AYIKA WA 1.    Gbigba ile ayika 2.   Fifo ile iwe wa ati ile igbonse 3.   Gige tabi riro oko ayika wa 4.   Ile sisa kiri ayika ile wa 5.   Dida ile nu si ibi ti o to 6.   Yiye ona tori agbara ojo AWON OHUN ELO IMOTOTO Ose, Omi, Pako tabi Ifoyin, Kanin-kanin, Ipara,Igbale, Ada, Oko, abbl.

ITESIWAJU LORI IRO/AMIN OHUN JSS2 (SECOND TERM)

  Amin tabi iro ohun ni iro aseyato   laarin oro meji tabi ju bee lo ti won ni sipeli kan naa subgon   ti itumo won yato   Apeere Igba – (time)   D D Igba - (calabash) R M Igba- (garden egg) D M   Oko – (hoe) R M Oko – (canoe) R D Oko- (husband) R R     Owo- (money) R M Owo- (Trade) D D   Ogun- (war) R R Ogun- (inheritance) R M Ogun- (medicine) D D Ogun –( god of iron) D M Ere- (python) R D Ere-(play)   R M Ere –(profit)   D D   Owo –( honor) D D Owo – (broom) R D Owo –(hand) R M   Amin lori awon oro olopo silebu Ogede –(banana) D D D Ireke –( sugar cane) D D M Opolopo – (abundance) D D R D Alangba –(lizard) R M D M Patapata – (completely) M M M M Igbagbo –(belief) D D M Oronbo-(orange) D R D M Atanpako –(thumb) D D D D D

OGUN PINPIN TABI JIJE NI ILANA IBILE SS2 (SECOND TERM)

Ogun toka si ohun ti ologbe fi oogun oju re ko jo nigba aye re. Ohun ini bee le je owo, ile, oko, , eru,omo, iyawo  tabi awon dukia miiran. Ni ile Yoruba bi omo se le je ogun baba naa lo le je ti iya ra. Ogoji ojo leyin  ti oku ba ti ku ni won to le pin ogun re. Won yoo yan baba isinku o le je ebi to ba dagba julo, oun ni yoo seto isinku titi di akoko ti won yoo pin ogun. Baba isinku kii mu ninu ogun. Ki ogun pinpin to waye, baba isinku ati awon amulegbe re yoo ti seto bi gbogbo nnkan  yoo fi lo ni irowo-irose. Ohun akoko ni lati da ifa lati mo ojo ti o ye ati akoko lati fi ijoko si.   AWON TI WON LETOO SI OGUN Gbogbo awon omo oku ati awon omo iya re ti won je aburo ni won ni eto si ogun. Baba , iya, egbon oku ati iyawo ko ni eto lati pin ninu ogun oku ni ile Yoruba. AKOKO TI A N PIN OGUN Leyin isinku ni won yoo dajo ti won yoo pin ogun. Ogoji ojo gbodo pe ayafi ti ija ba wa ti won si fe fi pinpin ogun petu si ikun-sinu to wa nile. OJO IJOKOO OGUN PINPIN Ona ti a n g...

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AYAN OGBUFO SSS1 (SECOND TERM)

  AayanOgbufo. Ayan ogbufo ni sise itumo ede kan si omiran. Ise ogbufo kuro ni   gbefe, o gba ki a ni imo lori ede mejeji, itumo awon ona ede bi owe ati akanlo ede inu ede ti a fe tumo ati ede ti a fe tumo re si . Ede Yoruba atata ati ilo amin ohun se Pataki ninu ise ogbufo alakoole. AAYAN OGBUFO ELEYO ORO Abandon                                    ko sile Abstain                                       Fa seyin Compare                                   ...

ASA ISINKU SSS2 (SECOND TERM)

  ASA ISINKU Iranse Olodumare ni awon Yoruba ka iku si. Iku kii gba riba tabi ebe, gbese ni iku, ko si eni ti ko ni san. Irin ajo si orun ni Yoruba ka iku si. Asa isinku ni eto ikeyin ti a n se fun oku. Awon orisirisi iku ti si n pani ni wonyii : Aisan, Ijanba lorisirisi, Iku aitojo, Fifowororiku. ETO ISINKU Eyi   ni eto isinku agbalagba ti o fi owo rori ku. 1.       IPALEMO ILE ATI OKU: bi oku ba ti ku, kii a to pariwo sita, a gbodo tun gbogbo ile se daadaa, ki a gbe oku si ori eni ti o dara. 2.      ITUFO : eyi ni ikede iku fun ebi ati aladugbo, ekun ni eni ti o ko ri oku yoo fi tufo fun awon ara ile. Bi oku ba se je ni a n tufo re. ti o ba je Oba a kii n so pe oba ku, oba waja ni won maa n so. Ti oba ba waja, won yoo koko se etutu, ki awon agbagba tabi ijoye ilu to tufo re. 3.      ITOJU OKU : won yoo we e mo pelu koinkion ati ose ni ehinkule. Okunrin ni we oku okunrin, ti obinrin si n we oku ob...

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)          ...