ASA ISINKU
Iranse
Olodumare ni awon Yoruba ka iku si. Iku kii gba riba tabi ebe, gbese ni iku, ko
si eni ti ko ni san. Irin ajo si orun ni Yoruba ka iku si.
Asa
isinku ni eto ikeyin ti a n se fun oku. Awon orisirisi iku ti si n pani ni
wonyii : Aisan, Ijanba lorisirisi, Iku aitojo, Fifowororiku.
ETO ISINKU
Eyi
ni eto isinku agbalagba ti o fi owo rori
ku.
1.
IPALEMO
ILE ATI OKU: bi oku ba ti ku, kii a to pariwo sita, a gbodo tun gbogbo ile se
daadaa, ki a gbe oku si ori eni ti o dara.
2.
ITUFO : eyi ni ikede iku fun ebi ati aladugbo, ekun ni eni ti o
ko ri oku yoo fi tufo fun awon ara ile. Bi oku ba se je ni a n tufo re. ti o ba
je Oba a kii n so pe oba ku, oba waja ni won maa n so. Ti oba ba waja, won yoo
koko se etutu, ki awon agbagba tabi ijoye ilu to tufo re.
3.
ITOJU OKU: won yoo we e mo pelu koinkion ati ose
ni ehinkule. Okunrin ni we oku okunrin, ti obinrin si n we oku obinrin. Ti o ba
je okunrin, won yoo wo ni ewu,sokoto ati fila, won yoo si fa irun, ge eekanna
owo ati tie se, ti o ba je obinrin won yow o ni ewu,iro ati gele, won yoo di
irun ori re. yato si aso ti won ba wo fun oku, won yoo tun fi orisirisi aso di i.
4.
TITE OKU NI ITE EYE: leyin oku wiwe, a o
fi aso funfun do oku. Gbogbo ebi yo da aso jo si egbe oku. Won yoo fi loofinda oloorun si ni ara, won fi owu
otutu di iho imu ati enu oku, won yoo se
eni tabi ibusun losoo ninu iyara tabi odede, awon obinrin ile yoo si maa kii ni
mesan-mewaa.
5.
IBANIKEDUN:
awon abenikedun yoo maa wole pelu omije loju, won yoo si maa ki awon omo
oloku teduntedun, awon omo oloku yoo si maa dupe lowo won pe awon naa yoo
gbeyin arugbo won.
6.
IBOJI OKU: awon ana ati omo oluko okunrin ni won
maa gbe ile oku. Iwon ese bata mefa ooro ni won yoo gbe. Ilepe inu re ni won n
lo lati yanju aawo to le waye laaarin ebi tabi awon omo oloku leyin isinku.
7.
ISINKU : eyi ni ayeye ikeyin. Ni oju oori, gbogbo ebi, omo ati ara
oloogbe yoo pese. Won yoo gbe oniruuru nkan wa bi eko tutu sinu posi ati owo
kan ha oku lowo. Bi won ba ti gbe posi sinu koto, akobi oku ni yoo koko bu
ilepa si oku lori leemeta.
ISINKU ABAMI
1.
ABUKE : won yoo yo ike re sinu ikoko kan, won yoo yo gbogbo ara re
sinu ikoko miiran, won yoo si wa ri ikoko mejeeji mole ninu igbo oro.
2.
OKU OMI : awon oniyemeja ni won n sinku eni ba ku si inu omi, eti
odo ti o ku si naa ni won yoo sin si.
3.
ENI TO POKUNSO : awon oloro ni won sin iru oku bee si
inu igbo oro.
4.
ENI JABO LORI IGI TABI IGI WO PA : idi igi ti o ba ku si ni won yoo sin si.
5.
OKU SANGO: eyi ni eni ti ara san pa. awon onisango
li n sin won.
6.
OKU OGUN: awon ologun-un lo n sin won. Eyi ni
awon ti won fi ibon pa, eni ti won fi ada tabi obe oa, abbl.
7.
OKU ADETE: Inu ahere ni won n gbe, ibe naa ni won
yoo sin si.
8.
OKU ABOYUN: awon oloro ni won n sin won si inu igbo
oro otooto ni won yoo sin oku ati ole inu re.
9.
OKU OMODE : won kii lo posi, akisa ni won yoo fi
sin ni aatan.
10. ONIGBESE: ori igi ni won n gbe oku bee ko, ti yoo
jera.
OKU RIRO
Bi
eniyan ba fura pe iku eniyan kan ti owo enikan wa, won le ro iru bee. Ibinu ati
ikanra ni oku ti won bar o maa n fi eni ti o seku paa lo laarin ojo meje.
Pls sir u only post the note on isinkun
ReplyDelete