Skip to main content

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

 


AKORI ISE : IPOLOWO OJA

Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta.

ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA:

(1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita  ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja

(2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja .

(3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA

Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri.

(i)             ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl

(ii)           ITO,:WO :Yoruba ni itowo ni adun obe”Eyi ni ki onibara to die wo ninu ohun ti o f era.Awon nnkan ti a le towo ni gaari,epo.aadun abbl

(iii)         ISIWO:Eyi ni ki a si nnkan ti a f era wo lati rii bi o se ri tabi gbo oorun re ti o n ta nnkan didi maa n si wo.

(iv)          OJA AWIN:Oloja le fun onibara re ni anfaani lati wa sanwo oja ti o ran i ojo miran.Awin ni ohun ti a r alai san owo.

BI A SE N POLOWO OJA

 

NNKAN TITA

ONA IPOLOWO

 

1

Agbado sise

Langbe jina o

Oruku ori ebe

Ibe oni o sooro

 

2

Agbon

Agbon gbo keke bi obi

 

3

Efo

E’refo,e’sebe o

Aje b’oko rerin in ofofo

 

4

Gaari

Gaari oloyo de o

Ayangbe gaari o

 

5

Iyan

Iyan-re,obe re

Ewoju obe e muyan

Kengbe’yan kolobe

 

6

Ewa sise

Lamuluke

Muke jina o

 

7

Moimoi

Moimoi epo

Moimoi elede

Oole mi rodo

 

8

Eko

E jeran eko

Ori bi ike

Paabo eko o

Oniyangi de o

 

9

Amala                     

Aroyi amala

Mo ro oyi o

 

10

Eja tutu

Gbetu omi akerese

Ki I dun l’odo

B’o de’le a do’yin

 

11

Iresi

Ofe niresi,eran lowo

 

12

Isu sise

Isu epo

O tu se’po muye

 

13

Oyin-igan

Oyin-igan re e

 

14

Elewedu

Elewedu t’oko de

E maa bo

 

15

Guguru ati epa

Guguru re e

Epa re e.

16

Robo

Robo egba re e

17

Egbo

O n yorii joo

O yoruku lala

18

Isana

Isana ale  o

Fere ni jo

Onisana n relee maa baa daro

19

Epo-pupa

Ere’po, e se’be o.

20

Epo oyinbo

Arokun epo oyinbo

21

Ila

Ee ko’la ore,

Ila ede re e o

22

Ogi

Ologi de  o

23

Ekoogbona

E dako mu o

24

Eba

Kengbe eba

Eba re e,eran re e

25

Adiye

Ee l’adiye ta bi,ara onile

 

IPOLOWO OJA NI ODE-ONI

Itesiwaju ti de ba ipate ati ikiri oja ni ode-oni.Oniruuru ona igbalode ni ipolowo oja n gba waye.

Apeere:

(1) IPOLOWO OJA NI ORI REDIO:Oniruuru ete ni won pa ni ori redio lati polowo oja.

(2) IPOLOWO NI ORI AMOHUNMAWORAN:Awon oloja n polowo ni ori ero telifi son.

(3) IPOLOWO NINU IWE IROYIN:Awon oloja maa n polowo oja won ninu iwe iroyin ojoojumo.

(4) LILO PATAKO OJU POPO:Awon ontaja yoo le aworan oja mo patako feregede ni oju titi lati polowo.

(5) IWE ILEWO PINPIN TABI LILE MO ARA OGIRI:Awon ontaja le ha iwe ilewo fun awoneniyan,won le fon ka aarin ilu tabi le won mo ara ogiri eba ona tabi oja.

(6) PIPATE OJA NINU ILE ITAJA: Awon ontaja maa n pate oja sinu soobu,ti won yoo le iye owo oja mo won lara.

(7) IKOPA NINU IPATE OJA: Eyi maa n waye ni awon ilu nla-nla bi Eko,Kaduna, ati bee bee lo lekan lodun.

(8) LILO ERO GBOHUNGBOHUN :Awon ontaja n lo gbohungbohun ni ori keke,alupupu tabi motolati polowo oja won.

ANFAANI IPOLOWO OJA;

1)    O maa n je ki won mo ohun ti a n ta

2)    O maa n je ki oja ya ni tita.

3)     O maa n je ki a ni onibara pupo.

4)    O maa n mu ki eto oro aje gbera soke.

      5)O maa n polongo oja jakejado ilu tabi agbegbe.

Comments

Popular posts from this blog

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gbagbo pe o ni ogun ati agbara

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                             AWON BATANI IHUN ORO/SILEBU Faweli-F = ka, ma,gbo,ran,sun, fe,lo, abbl. Faweli ati konsonanti ati faweli-FKF = Aja, obe, Adan, Erin, Ife, Iku Konsonanti ati faweli ati konsonanti ati faweli- KFKF =  Baluwe, Salewa, Jagunjagun, Kabiesi Konsonanti Aranmupe asesilebu – KF-N-KF =   gogo n