Skip to main content

OGUN PINPIN TABI JIJE NI ILANA IBILE SS2 (SECOND TERM)



Ogun toka si ohun ti ologbe fi oogun oju re ko jo nigba aye re. Ohun ini bee le je owo, ile, oko, , eru,omo, iyawo  tabi awon dukia miiran.

Ni ile Yoruba bi omo se le je ogun baba naa lo le je ti iya ra. Ogoji ojo leyin  ti oku ba ti ku ni won to le pin ogun re. Won yoo yan baba isinku o le je ebi to ba dagba julo, oun ni yoo seto isinku titi di akoko ti won yoo pin ogun. Baba isinku kii mu ninu ogun.

Ki ogun pinpin to waye, baba isinku ati awon amulegbe re yoo ti seto bi gbogbo nnkan  yoo fi lo ni irowo-irose. Ohun akoko ni lati da ifa lati mo ojo ti o ye ati akoko lati fi ijoko si.

 

AWON TI WON LETOO SI OGUN

Gbogbo awon omo oku ati awon omo iya re ti won je aburo ni won ni eto si ogun. Baba , iya, egbon oku ati iyawo ko ni eto lati pin ninu ogun oku ni ile Yoruba.

AKOKO TI A N PIN OGUN

Leyin isinku ni won yoo dajo ti won yoo pin ogun. Ogoji ojo gbodo pe ayafi ti ija ba wa ti won si fe fi pinpin ogun petu si ikun-sinu to wa nile.

OJO IJOKOO OGUN PINPIN

Ona ti a n gba pin ogun yato lati idile si idile. Awon miiran maa n pin ni olori-ojori.Olori-ojori ni pinpin ogun laaarin iye omo ti oloogbe bi. Akobi omokunrin ni yoo ko mu ogun, ti akobi omobinrin yoo si mu tele, leyin eyi ni awon toku yoo mu ogun.  Awon miiran si n pin in laaarin iye aya, eyi si ni a tun pe ni IDI-IGI. Pinpin ni ilana yii lo wopo julo ni ile Yoruba.  Ni ile Yoruba obinrin ti o ba bimo fun oko re ko leto ninu ogun oku.BI eru ba si bimo fun oloogbe, won maa n fun omo eru bee ni orun pupo nitori ile baba nikan ni o ni ko ni ile iya. Omo ale kii si ni eto si ogun ni ile Yoruba.

AWON OHUN TI A N JOGUN

1.   Awon nnkan to le tete baje

2.   Awon nnkan ti o le tete baje

3.   Aya oku

4.   Omo oku ti won ba kere

AWON OHUN TI A KII JOGUN

1.   Ile Oye

Ohun ini ilu

Comments

Popular posts from this blog

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

AWE GBOLOHUN (JSS)

 AWE GBOLOHUN   AWE GBOLOHUN ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa n se . ona meji Pataki ni awe gbolohun pin si . Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe, Olori awe gbolohun maa n da duro, yoo si ni itumo, o si maa n sise gbolohun abode. Apeere   1) Ola ti sun                2) Mo n bo   Awe gbolohun afarahe tabi afibo : eyi ni gbolohun ti ko le da duro ko si fun wa ni itumo, o maa darale olori gbolohun ni, o si maa n wonpo ninu gbolohun olopo oro ise ( onibo )   Lara awon atoka gbolohun afarahe ni : ti, pe, ki, iba, bi, boya, tabi ati bee bee lo. Awe gbolohun le wa ni   ibeere, aarin tabi ipari gbolohun. Isori meta ni a le pin si. Awon si ni : 1.     ASODORUKO 2.     ASAPEJUWE 3.     ASAPONLE AWE GBOLOHUN ASODORUKO : eyi ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko nipa lilo oro atoka   “PE” Apeere   : ...

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...