Skip to main content

APEJUWE IRO KONSONANTI SS1

 EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE

Apejuwe iro konsonanti

Iro konsonanti ni iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti a fi gbe won jade.

A le pin iro konsonanti si ona wonyi;

1. Ibi isenupe

2. Ona isenupe

3. Ipo alafo tan-an-na

Ibi isenupe: Eyi ni ogangan ibi ti a ti pe iro konsonanti ni enu. O le je afipe asunsi tabi akanmole.

 

Afeji-ete-pe. ( B, m)

Ete oke ati ate isale pade-apipe akanmole ati asunsi pade


Afeyin Fetepe ( f )

Ete isale ati eyin oke pade afipe asunsi ati akanmole pade


Aferigipe, (T d,s,n,r,l)

Iwaju ahon sun lo ba erigi oke . afipe asunsi ati afipe akanmole


Afaja ferigipe. ( J,s,)

Iwaju ahon sun kan erigi ati aarin aja enu. afipe ati afipe


Afajape (Y)

Aarin ahon sun lo ba aja enu. afipe asunsi ati akanmole


Afafasepe (K, g)

Eyin ahon sun lo kan afase .afipe asunsi ati akanmole


Afafasefetepe (Kp, gb,w)

Ete mejeji papo pelu eyin ahon kan afase . afipe asunsi ati afipe akanmole


Afitan - an-na – pe (H)

Inu alafo tan-an na ni a fi pe e



Ona isenupe: Eyi toke si iru idiwo ti awon afipe n se fun eemi ti a fi pe konsonanti, ipo ti afase wa ati iru eemi ti afi gbe konsonanti jade.

Asenupe

B,t,d,k,g,p,gb

Konsonanti ti a gbe jade pelu idiwo ti o po julo fun eemi afase gbe soke di ona si imu awon afipe pade lati so eemi, asenu ba kan na ni eemi inu enu ro jade nigba ti a si

Afunnupe

F,s,s,h

Awon afipe sun mo ara debi pe ona eemi di tooro, eemi si gba ibe jade pelu ariwo bi igba ti taya n yo jo

Asesi

J

A se afipe po, eemi to gbarajo ni enu jade yee bi awon afipe se si sile

Aranmu

M,n

Awon afipe pade lati di ona eemi, afase wale, ona si imu le, eemi gba kaa imu jade

Arehon

R

Ahon kako soke ati seyin, abe iwaju ahon fere lu erigi, eemi koja lori igori ahon

Afegbe-enu-pe

I

Ona eemi se patapata ni aarin enu, eemi gbe egbe enu jade

Aseesetan

W,y

Awon afipe sun to ara, won fi alafo sile ni aarin enu fun eemi lati jade laisi idiwo


Ipo tan-an-na: ibi alafo tan-an-na ni a fi n mo awon iro konsonanti akunyun ati aikunyun.


Konsonanti akunyun

D,j,gb,m,n,r,l,y,w

Awon konsonanti ti a gbe jade nigba ti alafo tan-an-na wa ni ipo ikun, eemi kori Aaye koja,eyi fa ki tan-an-na gbon riri


Konsonanti aikunyun

P,k,f,s,s,h,t

Eyi ni awon konsonanti ti a gbe jade nigba ti alafo tan-an-na wa ni ipo imi eemi ri aaye gba inu alafo yii koja woo rowo



Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                             AWON BATANI IHUN ORO/SILEBU Faweli-F = ka, ma,gbo,ran,sun, fe,lo, abbl. Faweli ati konsonanti ati faweli-FKF = Aja, obe, Adan, Erin, Ife, Iku Konsonanti ati faweli ati konsonanti ati faweli- KFKF =  Baluwe, Salewa, Jagunjagun, Kabiesi Konsonanti Aranmupe asesilebu – KF-N-KF =   gogo n

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gbagbo pe o ni ogun ati agbara

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)            ITO,:WO :Yoruba ni itowo ni adun obe”Eyi ni ki onibara to die wo ninu ohun ti o f era.Awon nnkan ti a le towo ni g