AGBEYEWO LITIRESO YORUBA
Afenuso ati atenudenu ni litireso awon Yoruba je laaarin
awon litireso toku fun opolopo odun ki o to di kiko sile.
Oniruuru eniyan ni won ti kopa ninu siso litireso Yoruba di kiko sile. Lara
won ni awon oyin ajihinrere ati awon onimo ede.
LITIRESO ni ise atinuda awon oloye lati inu iriri ati akiyesi
fun idanileko ati idanilaraya.
Litireso pin si ona meji :
1. Litireso alohun
1. Litireso apileko
Litireso
alohun: je litireso abalaja ti a jogun lati enu awon baba-nla-wa.
Ona meta ni litireso alohun pin si : EWI, ITAN AROSO ati ERE
ONITAN (Ere onise)
EWI : Oriki , Owe ati Alo apamo
ITAN AROSE : Alo apagbe, Itan iwase ati Itan akoni
ERE ONISE : Odun ibile , Egun alare
LITIRESO
APILEKO : Eyi ni awon litireso Yoruba
ti o di kiko sile sinu iwe fun kika, yale eyi ti a jogun lati enu awon
baba-nla-wa tabi ti awon oloye fi atinuda won gbe kale fun idanileko ati
idanilaraya.
Ona meta ni litireso apileko pin si :
1.Iwe itan aroso
2.Iwe ewi apileko
2. Iwe ere-onitan
IWULO LITIRESO
1. Maa fun ni ni ogbon , imo ati oye
2. O maa danilekoo ni pa asa awujo
3. O maa fi igbesi aye eda han
4. O wa fun idanilaraya
5. O maa fi ewa ede han
6. O maa mu itesiwaju ba ede
Comments
Post a Comment