Skip to main content

OYUN NINI. ITOJU ATI OMO SSS1 (FIRST TERM)


 

AKORI ISE: - OYUN NINI. ITOJU ATI OMO

Obinrin ti ko bimo ni leyin ojo pipe ni ile oko ni won n pe agan. Awon yoruba ka omo bibi si pupo, won gba pe ko si bi opo eniyan ti le po to ti ko ba bimo, aye asan ni oluwa re wa. Abiku nigba miran le so obinrin di agan.

 

OHUN TO N FA A KI OBINRIN MAA TETE LOYUN

1.     Bi nnkan osu obinrin baal ami tabi ti o n se segesege

2.     Oyun sise tabi isilo ogun ti o ba ile omo je

3.     Inu gbigbona

4.     Ti obinrin ba ya akiriboto tabi oko kura

5.     Ti nnkan omokunrin ba son

6.     Aisan atosi tabi jerijeri lara tokotaya

 

OHUN TI O LE FA OYUN BIBAJE LARA OBINRIN

1.     Aarun atosi olojo pipe

2.     Eda

3.     Awon Aje

4.     Ise agbara

           

Itoju oyun laarin osu kinni si iketa ko le. Obinrin ko gbodo naju. ki oyun re maa baa wale. oko gbodo maa ran an lowo ninu ise ile. leyin osu keta ni oko aboyun yoo to wa onisegun ti yoo maa toju aboyun lati ri pe oyun naa ko baje tabi bi omo ti ko pe ojo.

            A ajo fun aboyun leyin osu keta ni wonyii

1.     OYUN DIDE : -Bi oyun ba di osu meta ni won o ti dee . Ki oyun maa baje lara obinrin ni won se maa n de oyun titi di akoko ti yoo bimo. Osu kesan-an, tabi to ojo b ape ni won yoo to ja oogun na asile, ki aboyun si bimo.


2.     EEWO KIKA FUN ABOYUN : - Awon nnkan ti asa yoruba ko gbe aboyun laaye lati se ni an pe ni eewo. ona lati daabo bo oyun inu ni o bi eewo. Bi apeere

                 I.Alaboyun ko gbudo sise lile

               II.Alaboyun ko gbudo rin ninu orun tabi ni oru

              III.Ko gbodo je igbin, ki om ore maa ba dota

             IV.Oko aboyun to je ode gbodo sora pipa eranko abami ni akoko ti iyawo re wa ninu oyun.


3.     ASEJE FUN ABOYUN

4.     AGBO WIWE ATI MINU : Onisegun agbebi yoo se orisirisi aseje tabi agbo fun aboyun


5.     OSE AWEBI ATI AGBO ABIWERE : Ti oyun ba ti osu mejo onisegun yoo fun-un ni agbo abiwere, eyi yoo mu ara de.

 

 

ITOJU OYUN TI ODE ONI

Bi obinrin baa ti loyun ni yoo ti lo fi oruko sile ni ile iwosan ijoba ipinle tabi ibile ni agbegbe re fun ayewo ati itoju. Alaboyun yoo maa lo si ile iwosan bee loorekoore gege bi adehun tito ti yoo fi bimo.

       I.          Idanilekoo ati ayewo omo inu

     II.          Oogun ati abere

    III.          Ounje afaralokun

Comments

Popular posts from this blog

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON EYA ARA - IFO SS1

  AKOLE ISE: ATUYEWO AWON EYA ARA - IFO (EYA ARA ISORO) Eya ara ifo ni eya ara ti a maa n lo fun gbigbe iro ifo jade A le pin eya ara ifo si isori meji, awon ni; Eya ara ifo ti a le fi oju ri: apeere: ete oke, ete isale, eyin oke, e yin isale, evigi, aja enu, iwaju a lo n, aarin lion, eyin ahon, afase, ita gongongo, olele, aja-enu, kaa imu Eya ara ifo ti a ko le fi oju ri: Apeere; Edo-foro, komookun, eka-komookun, tan-an-na, inu gogongo, kaa ofun. AWON EYA ARA TI A FI N PE IRO EDE AFIPE: Afipe ni gbogbo eya ara ifo ti won kopa ninu pipe iro ede jede. A le pin awon afipe wonyi si meji; awon nii APIPE ASUNSI: Eyi ni afipe ti o le gbera nigba ti a aba n pe iro won maa n sun soke sodo ti aban soro. Apeere; Afipe asunsi ni, Ete Isale, Eju isale, iwaju alion, aarin alion, eyin ahon, olele. AFIPE AKANMOLE: Eyi ni awon afipe ti ko le gbara soke sugbon ti won maa n duro gbari bi a ba n pe iro jade. Apeere afipe akonmole ni, ete oke, aja-enu, afase, iganna ofun, eyin oke, erigi, olele. Ipo t...