ISORI
EKO : OWE ILE YORUBA
Owe ni esin oro , bi oro ba sonu owe
ni a fi n wa. Awon agba lo n pa owe lati yanju oro toba ta koko. Bi omode ba pa
owe niwaju agba , o gbodo wi pe “ toto o se bi owe.
AWON ONA TI OWE N GBA WAYE
I.
Akiyesi sise : awon agba maa n se akiyesi isele lati seda
owe. Apeere : Lala to roke , ile lo n bo
II.
Esin : opolopo awon owe ti awon babanla maa n pa waye lati
ninu esin ibile won. Apeere : Opele o seke, eni kii ni o gbofa
III.
Asa : awon agba a tun maa seda owe lati inu asa won. Apeere :
agba ko si ni ilu baje, bale ile ku, ile di ahoro
ORISIIRISII
OWE : isori marun-un ni a le pin owe Yoruba si. Awon ni.
OWE FUN IBAWI : bi enyan ba hu iwa ti ko dara, awon agba a
maa fi owe ba iru eni bee wi.
1. Ida n wo ile ara re, o ni oun
n ba oko je
2. Aifini peni, aifeeyan peeyan
ni mu ara oko san bante wolu.
3. Bi omode ba n se bi omode,
agba a maa se bi agba
OWE FUN IKILO : eyi ni a fi n pe
akiyesi eniyan ki o yere fun ohun kan, ise tabi iwa kan.
1. Agbojulogun fi ara re fosi ta
2. Alaso ala kii ba elepo sore
3. Ibi ko ju ibi , bi a se bi eru la bi omo
OWE FUN IMORAN : bi oro ba ruju awon
agba ni a n to lo fun imoran.
1. A kii peni ni ole ki a tun
maa gbe omo aran jo
2. Maluu ti ko ni iru oluwa niba le esinsin
3. Alagemo ti bi omo tire tan, aimo jo ku sowo omo alagemo
OWE FUN ALAYE : alaye ni baba oro,
awon owe kan wa ti awon agba fi n se alaye oro.
1. Eye ko so fun eye pe oko n bo
2. A kii toni ba gbe , ka maa to
oro baa ni so
3. Agbatan laa n gba ole, bi daso
fun ole a pa laro, bi a la ole nija, a sin in
dele.
OWE FUN ISIRI ; eyi ni awon agba lo lati tu eniyan ti ibanuje de ba ninu pe ki o ma se so ireti nu.
1. Pipe ni yoo pe, akololo yo pe
baba
2. Ki i buru titi ko ma ku
enikan moni, eniti yo ku ni a mo
3. Ise kii se ki omo eni maa
dagba
Comments
Post a Comment