Skip to main content

OUNJE ILEWA SSS1 (FIRST TERM)



 AKORI ISE – OUNJE ILEWA

 

Orisirisi ounje ni owa kaakiri ile Yoruba. Eya Yoruba kookan ni won fere ni ounje ti a mo won mo ti awon miran si je ka ri aye.

Niwon igba to je pe ise agba ni ise to gbajumo ju lo ni ile Yoruba, opolopo awon ounje ile Yoruba ni won je eyi ti a n ri eroja won lati ara nnkan ire oko bii isu, ege, agbado, eree, ogede ati beebee lo.

 

Awon ire oko ati ounje tia fi ri se Isu – Orisii isu to wa ni (i) Akosun Efuru, Apeere, koko, Iganagan (ii) Abo isu – Esoura, Oloo, Esuru, Anamo. Awon ounje ti a n fi isu se isu sise, isu – sisunje, Iyan(ekiti,ijesa,ondo) Amala, Isu (oyo/ibadan) dundu, Asaro, Ojojo(ife), Ebiripo(ijebu), Ikokore(ijebu), Anamo, Esuru.

 

EGE – Kaakiri ile Yoruba ni a ti nlo ege bii ounje, orisi ege meji ni o wa Egbe oniyan (Elentu) ati ege onigaari (Adan). Awon ounje ti a le fi ege se – Gaari(ijebu), Amala laafu(egba), fufu, pupuru(ikale/ilaje).

 

AGBADO – Kaakiri ile yoruba ni a ti n gbin-in. Eemeji lodun ni a maa n gbin Agbado. Agbado ojo ati Agbado eerun. Awon ounje ti a n fi agbado se – Ogi, ekomimu / jije, Ewa adalu, Guguru, Sapala(ife/ijesa), Aadun, Akara kango, Abari (moimoi agbado) Lapata (Akara agbado). Tuwo(igomina), kokoro otika, oti seke le / Burukutu.

 

OGEDE – Orisi ogede meji ni o wa, Ogede wewe / Abosan ati ogedeAgbagba – Ounje ti ale fi ogede se ni dodo, Amala ogede, Ipekere, Booli.

 

EREE – Orisi eree tabi ewa ni o wa, Eree nla, wewe, funfun, tabi pupa. Ounje ti a fi eree se ni – Adalu, Akara, Moimoi, Ewa wooro, Ekuru, Alape, Obe gbegiri.

 

OKABABA – A maa n fi se ogi mimu.

 

EGUSI – Egusi je ohun elo obe, Orisi egusi ni o wa, Itoo, bara. Ounje ti a le fi se obe, Ogiri, ororo

 

IRESI – Ounje Ile okeere ni iresi sugbon won n gbin ni agbegbe ijesa, Ekiti ati Agbadarigi. Ounje ti a le fi se sise je , Tuwo.

 

EYIN OPE – Ni a fi n se epo isebe, Ipete, Adi ati Emu.

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)          ...