ORISIRISI ORUKO NI ILE YORUBA.
Oniruuru
oruko lo wa ni ile Yoruba , awon ni wonyi
1. Oruko Abiso : awon oruko ti a so omo gege bi akoko ti a bi ati bi igba ti ri fun
awon obi re.
Apeere : Abiodun :omo ti a bi ni akoko odun Pataki
Fijabi : omo ti a
bi nigba ti ija wa ni aarin ebi.
Babajide
: omokunrin ti a bi leyin iku baba re agba.
Yetunde
: omobinrin ti a bi leyin iku iya re agba.
Abiona
: omo ti iya re bi si oju ona tabi oko.
2. Oruko Amutorunwa : eyi ni
oruko ti fun omo nitori ona ti a gba bi i
Apeere : Tayewo : akobi ninu ibeji.
Kehinde
:
omo ti a bi tele Tayewo.
Ige: omo ti o ba ese waye.
Ojo : omokunrin ti o gbe ibi re korun waye.
Aina :
omobinrin ti o gbe ibi re korun waye.
Dada
: omo ti irun ori to gbe waye ta koko.
Ilori
: omo ti iya ko se nkan osu ti o fi loyun re.
Ajayi: omo ti o doju bole nigba ti a bi
Ilori : omo ti iya re ko se nnkan osu nigba ti a
bi
Oke : omo ti yii ara re sinu apo waye.
Oni : omo to n ke tosan-toru
Idogbe: omo ti a bi tele idowu
OLUGBODI : omo ti o ni ika ese mefa
3. Oruko Abiku : Omotunde,
Kukoyi,Ekunsumi, Durojaye, Kasimaawoo, Bamitale
4. Oruko Oriki : OKUNRIN :-Alani, Alao, Aremu, Adisa,Talabi, Atanda Ajagbe. OBINRIN:-Amoke,Abebi,Aduke Ajoke,Ayoka,Awele, Ajihun,Aweni.
5. Oruko Inagije : Ajanaku,
Anifowose, Ajiyo, Ajisefinni
6. Oruko Esin tabi Orisa : Fabumi,
Sangoniyi, Ogunbiyi, Esuyemi, Efunsetan, Ojelabi
7. Oruko idile ajemo-ise Abinibi : Odebunmi,
Ogundele, Ayanwale, Akinwande, Awoniyi
Oruko
Idile ajemopo : Adeyemi, Sijuwade, Oyebisi, Agunloye, Kolawole, Ladigbolu,
Afolabi
Comments
Post a Comment