OHUN MIMO NINU ESIN IBILE
OPO OHUN ELO inu esin ibile je funfun, bi awon funfun se duro fun mimo.
Orisa funfun ni Obatala.
OHUN MIMO NINU ESIN IBILE
1. Ohun alawo funfun ni awon olusin Obatala, Oduduwa, Olokun,Olosun,Orisa Oko
ati Ifa maa n lo josin.
2. Awon orisa tabi abore ninu elesin orisa kan. Eni mimo ni won. Ojuse wa ni
lati toju ojubo orisa ati lati se irubo tabi etutu.
3. Ilebo/Ojubo Orisa ; o je ibi ti a ya soto ti a fi n bo orisa. O le wa
ninu ile, eyin odi ilu tabi aarin oja. O gbodo je ibi mimo.
4. Ounje Obatala :-iyan funfun ati obe ate ati egusi ni won fi n bo
Obatala.
5. Omi-aji-fowuro-pon ;- eyi ni omi ti obinrin ti ko i ti mo okunrin maa
n ji pon ni owuro kutukutu ni odo si ile orisa fun itoju alaisan aboyun ati
awon agan.
6. Iwa mimo :- iwa mimo ni awom elesin ibile fi n ba ara won lo. Bi
apeere : Awo kii san bante awo, eyi tumo si pe, ode kii gba iyawo ode egbe
re , bee naa won kii bura eke.
Ijora Esin Ibile Ati Esin Miiran
Ibamu die wa laarin esin ibile ati esin kirisitieeni ati musulumi
1. Igbagbo ninu Alarina :- Esin kookan ni alarina. Apeere Orisa :- alarina ni fun elesin ibile,
Jesu Kirisiti – Kirisitieeni, Momodu –Musulumi
2. Ile ijosin je ibi mimo- Ojubo awon elesin meteeta ni o je ibi mimo.
3. Nini Olori – Aworo je olori esin ibile, Pasito ati Imaamu ni Olori esin
iyoku.
4. Ofin – Eewo fun esin ibile. Ofin mewaa fun esin kirisiteeni. Saria fun
elesin Musulumi.
5. Aso funfun :- Imura awon elesin meteeta ni o jora.
Comments
Post a Comment