: ITAN
ISEDALE YORUBA LATI ILU-MEKA
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ ni wọ́n sọ nípa ìtàn Mẹ́kà pé láti ìlú Mẹ́kà
ni Odùduwà ti wá tẹ̀dó sí Ilé-Ifẹ̀.
Ní ìlú Mẹ́kà, Lamurudu je oba ni ile meka, o si ni omokunrin ti
oruko re je oduduwa. Odùduwà yapa sí ẹ̀sìn abínibí rẹ̀ tí í ṣe ẹ̀sìn Lámúrúdu
baba rẹ̀. Oduduwa ni aworo kan ti oruko re je Asara. Ìyapa yìí mú kí ìjà ńlá bẹ́
sílẹ̀ láàrin Odùduwà àti àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí. Bùràímọ̀, ọmọ Odùduwà pàápàá
lòdì sí Odùduwà baba rẹ̀ nítorí pé ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ní ṣe.
Inú bí Odùduwà, ó sì pàṣẹ̀ pé kí wọ́n sun ọmọ rẹ̀ náà ni ààye. Inú bí awọn ẹlẹ́sìn
Mùsùlùmí yòókù, wọn gbógun ti Odùduwà, inu rogbodiyan yii ni Lamurudu ku si.
Odùduwà ati awon eniyan re sá àsàlà kúrò ní Mẹ́kà, won sir in inu aginju fun
osu meta ki won to de Ile-ife. Won sì tẹ́dò sí Ilé-Ifẹ̀. Bayi ni Oduduwa se di
ara Ile-ife ti o si fi ibe se ibudo. Ó bá Àgbọnmìrègún tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sẹ̀tílù.
Àgbọnmìrègún yìí ló dá ẹ̀sìn ifá silẹ. Ìtàn náà tẹ síwájú láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀
pé Ilé-Ifẹ̀ ni àwọn ọmọ Yorùbá yòókù ti lọ.
Àwọn kan sọ pé Ọ̀kànbí
nìkan ni ọmọ Odùduwà tí Ọ̀kànbí sì wá bí àwọn ọmọ méje tí wọ́n jẹ́ ọba Aládé
káàkiri ibi tí a lè tọpasẹ̀ àwọn Yorùbá dé lónìí. Àwọn mìíràn gbà pé àwọn méje
wọ̀nyí kì í ṣe ọmọ-ọmọ Odùduwà, pé ọmọ Odùduwà gan-an ni wọ́n àti pé kì í ṣe
ìyàwó kan ṣoṣo ni Odùduwà ni.
Comments
Post a Comment