ISORI ORO
Orisii isori oro mejo ni o wan i ede Yoruba.Awon ni :
1) Oro-Oruko (Noun)
2) Oro-Aropo-Oruko
(Pronoun)
3) Oro-Aropo-Afarajoruko
(Pronominals)
4) Oro-ise
(Verb)
5) Oro-Apejuwe
(Adjective)
6) Oro-Aponle (Adverb)
7) Oro-Atokun
(Preposition )
8) Oro-Asopo (
Conjunction )
Awon isori ninu gbolohun ni awon wonyi : Oro oruko, Oro
aropo oruko , Oro ise, Oro apejuwe, Oro aponle, Oro asopo, Oro atokun.
ORO ORUKO : Eyi ni n oro ti a n pe nkan. O le je oruko eniyan,
eranko, ibugbe, ibikan tabi nnkan.
Oro oruko maa sise bi oluwa, abo tabi eyan ninu gbobohun.
Apeere : Kola jeun - Ipo oluwa . Mo ra iwe - Ipo abo . Tunde pa eja obokun -- Eyan
ORO
AROPO-ORUKO : Eyi ni awon oro ti a n lo dipo
tabi ropo oro oruko ninu gbolohun.
Apeere : Mo, O, A,
E, Won, Mi, Wa, Yin, Awa, Awon, Iwo, Eyin.
Apeere :
1.
Mo je
eba.
2.
Won ti lo.
3.
Kehinde ri yin.
4.
Awon oluko ko ti
de e.
ORO-ISE : Oro-ise ni koko
tabi opomulero oro ti o n toka si isele tabi ohun ti enikan se ninu gbolohun.
Apeere :
1.
Femi rerin-in.
2.
Adeoti ra aja
3.
. Salako jokoo.
4.
Ode pa ejo.
ORO APEJUWE : O je oro to ma n sise eyan ninu gbolohun. Oro-oruko ni
o maa yan. Bi apeere :
1.
Adie funfun ni Ojelade fi bo eegun
2.
Epo pupa die ni ki o bu si
3.
Obinrin kukuru ni Daniella.
ORO APONLE : O je oro ti o maa n sise epon/eyan ninu gbolohun. Eyi a maa se afikun itumo fun
oro-ise ninu gbolohun. Bi apeere :
1.
Alaaare naa
sun die
2.
Akinwande
sun gbalaja
3.
Femi ga gbongbonran.
ORO ATOKUN : Eyi ni oro ti o maa n saaju oro-oruko ti o jeyo nipo
abo ninu gbolohun. Eyi a maa fi ibi ti eniyan tabi nnkan ti sele.
Bi apeere :
1.
Olubisi ti eko de
2.
Kolawole wa ni Ibadan
3.
Mo ti wa si ile ti pe
4.
Won de ni ana
ORO ASOPO : Eyi ni awon oro ti a fi n so oro meji po. Iru awon oro
ti a ba fe sopo maa n je isori oro kan naa. A maa lo lati fi ajumobarin tabi
iyipada han laaarin oro meji.
Bi apeere :
1.
Ayan ati Sola lo se ise naa
2.
Ajayi oun Ojo ni won tun ile se
3.
Iwo pelu emi ni a maa jo jeun
4.
Wunmi o le
sun afi ti o ba ri Kemi

Comments
Post a Comment