ISORI EKO : ISOMOLORUKO NI AYE ATIJO
Bi awon Yoruba se ka omo bibe si naa ni won
ka isomoloruko si. Isomoloruko je ohun ariya ati ayeye. Awon oruko ti a maa pe
omo saaju ojo isomoloruko ni wonyi :
Ikoko, Tunfulu, Arobo, Alejo
Okan
ninu agba obinrin ile yoo ti fa irun ori ikoko, won yoo wo aso fun un. Iyale
ile tabi agba okunrin ni n seto
isomoloruko.
Owuro kutu tabi owo iyaleta ni won n so omo
loruko. Ojo keje ni a saaba n so omobinrin ni oruko, ojo kesan-an ni omokunrin,
ti ibeji si je ojo kejo Won dupe lowo olorun fun ebun nla ti o fun idile naa,
bakan naa ni won yoo juba baba-nla omo.
Leyin eto yii ni won yoo ko eroja isomoloruko
si ori tabili ni oju agbo. Iyale ile tabi bale to n dari eto yoo kede
oruko ati itumo won ni kookan, awon ebi
yoo si maa so owo si inu omi, leyin ni adari eto yoo maa fi awon eroja
isomoloruko ni okookan bee ni yoo si maa
fi se adura fun omo.
AWON OHUN ELO ISOMOLORUKO
- Omi – Itura aye : omo naa ko ni ri inira
- Ataare – Opo omo tabi asepe oore : ki omo naa di iru , ki o di igba
- Orogbo – Emi gigun : omo naa yoo dagba , yo dogbo
- Obi – Emi gigun : obi ni bi iku, obi ni bi arun, omo naa ko ni ku ni rewerewe
- Oyin , Aadun, Ireke, Iyo – Igbadun : ki aye omo naa kii o dun
- Oti - Ajinde ara : oti kii ti, oti kii sa, aye omo naa ko ni ti
- Epo – Ero : ki aye omo naa ki o ri irorun
- Eku/Eja – jije aye pe ati lila isoro : isoro ko ni bori omo naa
- Owo - Riri owo na : omo naa yo ri owo fi s’aye
Comments
Post a Comment