ISEDA
ORO ORUKO
Iseda
oro oruko ni siseda oro oruko titun ninu
ede Yoruba. Awon ona ti a le gba seda
oro oruko titun ni wonyii
1.
Lilo afomo ibere
2.
Lilo afomo aarin
3.
Sise apetunpe
4.
Sise akanpo oro oruko
LILO AFOMO IBERE . A le
seda oro-oruko titun nipa lilo afomo ibeere, awon wuren afomo-ibere ni : a, e,
I ,o, ai, ati, oni, alai ati bee bee lo.
|
AFOMO IBERE |
MOFIMU ADAADURO |
ORO ASEDE (ORO-ORUKO) |
|
A |
Kede |
Akede |
|
E |
Bi |
Ebi |
|
I |
Tiju |
Itiju |
|
O |
Laju |
Olaju |
|
Ai |
Mo |
Aimo |
|
Ati |
Je |
Atije |
|
Alai |
Gbon |
Alaigbon |
|
Olu |
Ko |
Oluko |
|
Ee |
Kerin |
Eekerin |
LILO AFOMO AARIN :
Aarin oro-oruko meji ni a o fi afomo aarin bo lati seda oro-oruko titun.
|
ORO-ORUKO |
AFOMO AARIN |
ORO-ORUKO |
ORO ASEDA |
|
Ori |
Jo |
Ori |
Orojori |
|
Odun |
Mo |
Odun |
Odunmodun |
|
Iran |
Ki |
Iran |
Irankiran |
|
Ile |
Si |
Ile |
Ilesile |
|
Iso |
Ku |
Iso |
Isokuso |
|
Opo |
Ni |
Opo |
Opolopo |
|
Igba |
De |
Igba |
Igbadegba |
LILO
APETUNPE : APETUNPE APOLA ORO-ISE
|
ORO-ISE |
ORO-ISE |
ORO
ASEDA |
|
Wole |
Wole |
Wolewole |
|
Rerun |
Rerun |
Rerunrerun |
|
Jagun |
Jagun |
Jagunjagun |
LILO
APETUNPE : APETUNPE ORO-ORUKO
|
ORO-ORUKO |
ORO-ORUKO |
ORO
ASEDA |
|
Odun |
Odun |
Odoodun |
|
Egbe |
Egbe |
Egbeegbe |
|
Osu |
Osu |
Osoosu |
LILO
APETUNPE ELEBE
|
ORO-ISE |
KOSONANTI
TO BERE ORO-ISE |
MOFIMU
‘I’ |
ORO
ASEDA |
|
Lo |
L |
I |
Lilo |
|
Gbe |
Gb |
I |
Gbigbe |
|
Je |
J |
I |
Jije |
LILO
AKANPO ORO-ORUKO : Lilo akanpo oro-oruko meji maa n mu ki isunki tabi aranmo
waye ni opo igba. Bi apeere
|
ORO-ORUKO |
ORO-ORUKO |
ORO
ASEDA |
|
Omo |
Obinrin |
Omobinrin(isunki) |
|
Oju |
Ile |
Ojule(isunki) |
|
Agbo |
Ile |
Agboole(aranmo) |
|
Ile |
Iwe |
Ileewe/Ile-iwe(aranmo) |
AKANPO
AFOMO IBERE “Oni” MO ORO ORUKO MEJI
|
AFOMO
IBERE |
ORO
ORUKO |
ORO
ORUKO |
ORO
ASEDA |
|
Oni |
Ori |
Ire |
Olorire |
|
Oni |
Aya |
Oba |
Alayaba |
|
Oni |
Owo |
Ile |
Olowoole |
|
|
|
|
|
SISE
ASUNKI ODIDI GBOLHUN DI ORO ORUKO
|
GBOLOHUN |
ORO
ORUKO TI A SEDA |
|
Oluwa to
sin |
Oluwatosin |
|
Ifa ni
eti |
Ifaleti |
|
A kuru
yejo |
Akuruyejo |

Comments
Post a Comment