Skip to main content

ISE ORO ORUKO ATI AROPO ORUKO NINU GBOLOHUN JSS3(FIRST TERM)

 


ISE ORO ORUKO ATI AROPO ORUKO NINU GBOLOHUN

 

Oro-oruko (Noun) ni awon oro ti won le da duro ni ipo Oluwa,Abo tabi Eyan ninu gbolohun.

Bi apeere :

OLUWA (Subject) : Oluse isele inu gbolohun ni oluwa. Ibere gbolohun ni o maa n saba wa.Apeereoro-oruko ni ipo oluwa ni a fala si nidii yii:

                                                    i.     Bola lo si Ibadan.

                                                  ii.     Ayo jeun yo.

                                                iii.     Alaafia to Ayo.

ABO: (Object) Abo ni olufaragba nnkan ti oluwa se ninu gbolohun.Abo le je yon i aarin tabi ipari gbolohun.Apeere oro-oruko ni ipo abo ni a fala si nidii yii:

                                          I.               Oluko ri Bisi lanaa.

                                       II.               Mo lo si Ibadan ni ijeta.

                                     III.               Sola te Eba.

EYAN (Qualifier)   Ti oro-oruko meji ba telera ninu apola-oruko keji ni eyan oro-oruko akoko ni o yan .Apeere eyan ni a fala si nidii yii:

                                i.                         Iwe Iroyin dara lati ma aka.

                              ii.                         Mo ri Aja Ode

                            iii.                         Eja Aro ni mo ra.

ORO-AROPO-ORUKO (Pronoun) :  Oro-aropo-oruko ni awon oro ti a n lo dipo oro oruko  ninu gbolohun .Bi apeere : Mo,  O,  A, E, Won, Mi, Wa, Yin, Awa, Awon, Iwo, Eyin.

a.      Bolatito ra iwe=O ra iwe           ‘O’ duro fun Bolatito

b.     Olu ati Akin wa =Won wa         ‘Won’ duro fun Olu ati Akin.

Apeere oro-aropo oruko oluwa (Subject)

1.     Mo je eba

2.     O ti de

3.     Won ti lo

4.     A lo oko

Apeere  oro-aropo oruko abo(Object)

1.     Tolu ri mi

2.     Sade n pe wa

3.      Ola ri yin

Apeere  oro-aropo oruko eyan (Qualifier)

1.     Aso mi tutu

2.     Ile yin dara

3.   Bata re wu mi

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

AWE GBOLOHUN (JSS)

 AWE GBOLOHUN   AWE GBOLOHUN ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa n se . ona meji Pataki ni awe gbolohun pin si . Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe, Olori awe gbolohun maa n da duro, yoo si ni itumo, o si maa n sise gbolohun abode. Apeere   1) Ola ti sun                2) Mo n bo   Awe gbolohun afarahe tabi afibo : eyi ni gbolohun ti ko le da duro ko si fun wa ni itumo, o maa darale olori gbolohun ni, o si maa n wonpo ninu gbolohun olopo oro ise ( onibo )   Lara awon atoka gbolohun afarahe ni : ti, pe, ki, iba, bi, boya, tabi ati bee bee lo. Awe gbolohun le wa ni   ibeere, aarin tabi ipari gbolohun. Isori meta ni a le pin si. Awon si ni : 1.     ASODORUKO 2.     ASAPEJUWE 3.     ASAPONLE AWE GBOLOHUN ASODORUKO : eyi ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko nipa lilo oro atoka   “PE” Apeere   : ...