Skip to main content

ISE ABINIBI ILE YORUBA SSS1 (FIRST TERM)


 

ISE ABINIBI ILE YORUBA

Awon baba nla i a ka ise si pupo. Won gbagbo wi pe ole a lapa. Idi niyi ti won fi wi pe awon arisemase ni ole darun ise sise je olubori ninu asa Yoruba. Iran yoruba kookan ni won si ni ise abinibi bii ise asela to tun je ase file omo lowo

A le pin ise abinibi Yoruba si ona merin wonyi.

1.      Ise Agbe

2.      Ise Ode

3.      Ise Owo

4.      Ise Ona

 

1.      Ise Agbe. Ise agbe je ise ti gbajumo ju lo ni ile Yoruba. Ise agbe se Pataki nitori awon ni won n pese ounje fun ara ilu.

A le pin ise agbe si meji wonyi

a)      Agbe Alaroje ni awon agbe kekeke ti won n la oko etile, oko ogba tabi oko akure fun jije ebi won.

b)      Agbe Aladaa-nla, awon wonyi ni won n fi ise agbe se ise je, won mu ise yii ni okun-kundun. Awon ohun ti won n gbin ni koko obi, orogbo, ope, osari, kofi koba, agbon abbl

Iwulo Ise Agba

                                                          I.          Awon ni won n pese ounje fun ara ilu

                                                        II.          Awon ni pese ohun elo fun awon ile-ise gbagbo

                                                       III.          Ara ohun ti won n gbin ni a fi sowo soke okun

Ohun elo ise agbe

(i)                Aake (axe)    (ii) Oko (hoe)       (iii) Ada (cutlase)               (iv) Apere (basket)

 

2.      ISE ODE :- Ni ise to gbajumo ni ile Yoruba, awon ni o si tun n pese awon eran ti arije ni ile Yoruba, awon ode ni won n daabo bo ilu, awon ni o si tun n pese awon eran ti arije ni ile yoruba.

Ise ode pin si meta yii

a)      Ode Igbe, awon ni ogboj n ode ti won ni sode oni ninu igbo kijikiji awon ni won npe eran bi ekun, inaki kinni un agbon rin abbl.

b)      Ode Etile, awon wonyii ni won n le oko etile, awon ni won naa n pa awon eran kekeke bi oya okere, okete abbl.

c)      Ode Asode – ni awon ode ti won n so aarin ilu ni oru  nitori awon ohasa

 

Iwulo ise ode

a)      Awon ode ni won n se ilu ni o ru nitori awon olosa

b)      Awon ni won rijagun, ti won si daabo bo ilu ni akoko ogun.

c)      Won maan se etitu fun alafia ilu

d)      Won  n pa eran igbe fun oba to bafe se alejo tabi odun

 

3.      ISE OWO – Awon ise owo to gbajumo laarin awon Yoruba ni wonyii.

Aso inihub, Aso dida, Eni hihun Epo fifo ilu—lilu, isegun ati bee bee lo.

                           I.          ASO HIHUN : eyi je ise abinibi ni agbegbe oyo, owu ibile ni won fi n hun aso. Awon ohun elo ni : keke-owu,pangolo,Apesa,Kokogun, Owu abbl.

                         II.          ENI HIHUN :- ipinle Osun ati Ekiti ni eni hihun ti gbajumo julo. Tokunrin tobinrin lo n se ise yii. Ohun elo :- aro, Obe, Iko,Paiko.

                        III.          ARO DIDA : -awon obinrin ni won maa n sise yii. Ohun elo:- Ikoko-nla, omi.Aro,Iko.

                        IV.          ILU LILU:- Awon iran ayan lo n lu ilu, ise abinibi si ni pelu. Amuludun ni awon onilu je. Orisirisi ilu ti won maa n lu ni ; Bata fun sango ati Egungun, Agere Ogun ni won n lu fun un. Dundun, Gangan,Iya-ilu,Bembe,Samba,Sakara fun ayeye sise bii Oye jije, Igbeyawo abbl.

                         V.          ISE ISEGUN :- awon onisegun ni won n ja ewe, wa egbo fi se itoju alaisan.

4.      ISE ONA – Awon ni ise Agbede, ise gbenagbena, Epo fifo, Ikoko mimo, Igba finfin, irun didi, onigbajamo.

                           I.          ISE AGBEDE:- awon alagbede ni won n ro oko,ada,ibon ati aake. Awon irinse won ni Omo-owu, Owu, Emu,Ikoko-Omi, Ewiri, abbl.

                         II.          GBENAGBENA :- eyi jemo ise igi gbigbe tabi didara si ara igi. Ohun elo :- Aake, Ada, abbl.

                        III.          EPO FIFO:- ise iran Aresa ni. Awon okunrin ni ko eyin lati ori igi opo, awon obinrin ni won n fo epo ni eku. Ohun elo :- Igba ope,Ikoko-nla,Abo, abbl.

                        IV.          IGBA FINFIN :-Ise Onirese ni ise yii. Awon afingba maa n dara orisirisi  si ara igba. Okunrin ni o wopo nidi ise yii. Ohun elo:- Obe, Sekele.

                         V.          IRUN DIDI:- Ise obinrin ni, Ohun elo:- Ilari, Owu-Idirun, Apoti, Adi-Agbon,Iyarun, abbl.

                        VI.          ISE GBAJAMO :- ise okunrin ni. Awon ni won maa n ge irun tabi fa irun fun okunrin. Ohun elo:-Abetele, Abe Ifari, Olukondo, Iyarun,abbl.

Comments

Popular posts from this blog

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)            ITO,:WO :Yoruba ni itowo ni adun obe”Eyi ni ki onibara to die wo ninu ohun ti o f era.Awon nnkan ti a le towo ni g

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gbagbo pe o ni ogun ati agbara

ITOJU ARA ATI AYIKA JSS3 (SECOND TERM)

Eyi ni sise ara eni losoo tabi sise ara loge. Iwa obun ni idakeji imototo. Awon Yoruba korira iwa obun pupo nitori pe o le fa aisan saye eni. ONA TI A LE GBA TOJU ARA ENI 1.    Iwe wiwe 2.   Enu fifo 3.   Irun didi tabi gige 4.   Eekanna gige 5.   Aso fifo 6.   Fifi adi agbon tabi ipara pa ara leyin iwe wiwe 7.    Itoju ounje wa 8.   Lilo ogun to ye : Ilokilo ogun ko dara ONA TI A GBA TOJU AYIKA WA 1.    Gbigba ile ayika 2.   Fifo ile iwe wa ati ile igbonse 3.   Gige tabi riro oko ayika wa 4.   Ile sisa kiri ayika ile wa 5.   Dida ile nu si ibi ti o to 6.   Yiye ona tori agbara ojo AWON OHUN ELO IMOTOTO Ose, Omi, Pako tabi Ifoyin, Kanin-kanin, Ipara,Igbale, Ada, Oko, abbl.