IPO OLODUMARE NINU ESIN IBILE
Yoruba gba pe enikan wa ti o ni agbara ti o ga ju gbogbo eda aye
lo. Eni nla yii ni won n pe ni Olodumar, Eledaa, Atererekaye, Alala-funfun,
Oba-orun, Olumoran okan ati bee bee lo.
Won gbagbo pe Olorun tobi ju gbogbo eda lo, o si ye ni eni ti a n
bu ola ati iteriba fun un. Awon Yoruba n fi ise owo re ni won se pe ni awon
oruko bayi:
1. ELEDAA &
ASEDA : Eni ti o da ohun gbogbo ni orun ati
aye
2. OLORUN : Olu
Orun : eyi ni Oba orun
3. OLODUMARE :
Won fi Olorun we ODU. Eyi ni ohun ti o tobi julo.
4. ATEREREKAYE
: Titobi ati ola re kari gbogbo aye.
5. OBA-A-BOJU-LU-KARA-BI-AJERE:
Eni ti o ri ohun gbogbo ti eda se .
Ninu asa Yoruba, Olorun ni oruko Oba bi apeere : Oba awon Oba, Oba
Aiku, Oba airi, Oba ti o ju oba lo. Won fi titobi ati agbara re we ti Erin ninu
igbo, won pe ni AJANAKU ti n mi igbo kijikiji, won a tun ma pe e ni
A-duro-gbon-in-gbon-in leyin asooto.
DIE LARA AWON ORUKO TI YORUBA PE OLODUMARE : Olugbala, Oludande,
Afunnimasinregun, Adakedajo, Olojo-oni, Oga-ogo, Oyigiyigi, Olumoran-Okan,
Atoobajaye, Alapagbogboro-ti-i-yomo-re-lofin, Ogbagba-ti-gba-alailara,
Apata-ayeraye, Awimayehun. Adanimagbagbe, Awamaridi ati bee bee lo.
dhh
ReplyDelete