ISORI EKO :
Eto Iselu Abinibi Nile Yoruba
Ki
awon oyinbo to de ile Yoruba ni awon babanla wa ti ni eto oselu to fi ese mule gboingboin. Eto oselu beere lati inu
ile. Ipa ti baale ile, iyaale ile, obinrin ile, omo ile, awon oloye ati oba ilu
ko ninu eto oselu ko kere. Awon ni won mu ilu ro nipa eto idajo ododo, aabo to
gbamuse, igbega ati idagbasoke to se mu
yangan.
AATO
AGBBO ILE
Eto
ogbole ni ipinle eto iselu ni ile
Yoruba. Agbole ni ibe ti awon ebi tabi alajobi n gbe papo. Baba, iya, egbon ,
awon omo ati awon ibatan ti won to ese baba waye.
Agbole
ile le to mewa si meedogun. Bi agbole ba se tobi si ni awon eniyan ibe se maa n
po si. Olori agbole ni baale. Oye idile ni, eni ti o ba dagba ju lo ninu ile ni
n je oye baale.
ISE
BAALE ILE
1.
Aawo pipari
2.
Alejo gbigba
3.
Lile alejo to ba se kuro ni agbo ile
4.
Adari eto ayeye ebi
5.
Imojuto omo ile
6.
Asoju ebi ni ibi ipade adugbo tabi ilu.
ISE
IYAALE ILE
1. Olori ati
asoju awon obinrin ile
2. Iya agbebi
3. Olutoju asa
ati ise ebi
4. Aawo pipari
ISE
OBINRIN ILE
1. Itoju ile
ati ayika
2. Ina dida
3. Mimu ayeye
larinrin
4. Gbasa niyi
(ekun sisun nibi isinku)
5. Itoju iyawo
titun, iya ikoko ati omo
6. Eyin eran
gbigba ni ipade ayeye molebi
ISE
OMO ILE
1. ise ilu ati
ti ebi sise ( oko riro)
2. Eran pipa
nibi ayeye
3. Iranwo ni
igbejo Baale
ETO IDAJO NI
AGBOOLE
Igbejo
maa n wa laarin agbo ile lati yanju aawo to ba suyoi. Baale ati awon agbaagba
ni won n jokoo yika ni igbejo . bi ija
ba wa, awon ni yoo pari re, ti won yoo fi ase le e.
Iyaale
ati awon iyawo ki I jinna si igbejo Baale bee ni awon omo kekere naa maa n woran
nitori “omode oni ni agba ola”
ETO
ISELU ADUGBO.
Adugbo
je ibi to tobi die , adugbo kan le ni to
agbo ile marun-un si mewaa. Baale ni a
pea won olori ileto tabi ilu kekere, abe Oba alade kan ni baale maa n wa.
Gege
bi eto iselu ibile , baale gbodo gba ase lowo oba alade to n sin ni abe kii o
to le se ohun Pataki Kankan ni ilu re, bee o ni lati jabo fun Oba bi nnkan se n
lo si. Baale naa maa ni awon baale ati awon ijoye kekere tire ti won jo n selu
ni adugb won.
OBA ALADE
NINU ETO OSELU
Ni
ile Yoruba Oba alade ni alase ati olori ilu, o si ni ase ati agbara lori gbogbo
ibi ti ile ilu re de. Oba le pa, o si le gbala, oun asiwaju ilu ninu esin ati
ayeye.
Olowo
ilu, olola ilu, oloogun ilu, ijoye ilu, tomode tagba ilu ti Oba ni won se. bi
agbara ati iyi Oba se to ko le da se ilu. Oba ni awon igbimo ti won ran lowo
ninu eto iselu, awon oloye ati bale ni won jo n se ijoba julo, awon aworo
orisa, babalawo ati awon olori egbe n je iranwo fun Oba nipa fifun Oba ni
imoran ati atileyin. Awon odo ilu na ni ipa ti won ko ni eto iselu. Iyalode ni
olori awon obinrin ilu, maje-o-baje ni awon obinrin je fun ilu.awon ni iyaloja,
iyalaje, obinrin a si maa je Adede nigba ti Oba ba waja.
Comments
Post a Comment