Skip to main content

ESIN ODE-ONI SSS2 (FIRST TERM)

 


ESIN ODE-ONI

Esin ni ona ti awon eniyan gba sin olorun, ko si aniani pe awon Yoruba ti ni esin ti won se ki awon Larubawa tabi awon oyinbo to ko esin musulumi ati esin kirisiteeni de aarin won. Beeni awon esin ajeji wonyii se n de ni awon Yoruba n gba won mora pelu oyaya.

Awon esin ode oni ni esin musulumi ati esin kirisiteeni. Awon esin miran ti won tun n gbile laarin wa ni esin Ekanka, Gurumaraji ati Buda.

Esin  musulumi

Eyi ni esin ajeji ti o koko de ile Yoruba. Awon Larubawa ni won mu esin yii de. Itan fi ide re mule pee sin musulumi ti de ile Yoruba saaju ogun jihad ti Utman Dan Fodio gbe dide ni odun 1804

Imaamu gege bi olori elesin ni o n saaju irun .

EEWO AWON ELESIN MUSULUMI.

1.     Won kii wo bata woo inu mosolasi, enu ona ni won n bo o si

2.     Apa ila orun ni won n koju si kirun

3.     Obinrin ati okunrin kii kirun po, otooto ni won maa n duro.

4.     Obinrin ko le saaju irun

OJUSE WON

1.     Igba marun ni won gbodo kirun lojumo

2.     Won gbodo gba awe fun ogbon ojo ninu ose Ramadaani.

3.     Bi owo ba wa, won le lo Meka leekan ni igbesi aye won.

4.     Musulumi kii je eran elede

EKA MUSULUMI.

Orisi eka musulumi ni : Ansaru, Amadiya< Tijani<Metasinni, abbl.

ODUN AWON MUSULUMI

Orisi odun meta ni musulumi n se ninu odun. Awon si ni

1.     Id-el-kabir

2.     Id-el-fitri

3.     Id-el-maulud.

ESIN KIRISITEENI

Awon oyinbi ni won mu esin kirisiteeni de ile Yoruba ni bi odun  1840 leyin  igba ti won fi ofin de owo eru, ti won si ko awon adulawo pada si ile saro. Ile Saro yii ni awon ajiyinrere pelu atileyin Samuel Ajayi Crowther ti wa si Ile Yoruba lati tan esin naa kale. O le ni oodunrin (300) odun tie sin Musulumi ti de ile Yoruba ki esin yii to de .

EKA ESIN KIRISITENI

1.     Katoliiki

2.     Metodiisi

3.     Onitebomi

4.     Siesi

5.     Sele

6.     Kerubu

7.     Pentikosita, abbl.

ODUN AWON KIRISITEENI ATI AKOKO TI WON  N SE WON.

1.     Odun nla (new year day)       Jan  1

2.     Odun Ajinde    (Easter )          April

3.     Odun keresimesi (Christmas) Dec 25

4.     Boxing day        Dec 26.                     

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

AWE GBOLOHUN (JSS)

 AWE GBOLOHUN   AWE GBOLOHUN ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa n se . ona meji Pataki ni awe gbolohun pin si . Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe, Olori awe gbolohun maa n da duro, yoo si ni itumo, o si maa n sise gbolohun abode. Apeere   1) Ola ti sun                2) Mo n bo   Awe gbolohun afarahe tabi afibo : eyi ni gbolohun ti ko le da duro ko si fun wa ni itumo, o maa darale olori gbolohun ni, o si maa n wonpo ninu gbolohun olopo oro ise ( onibo )   Lara awon atoka gbolohun afarahe ni : ti, pe, ki, iba, bi, boya, tabi ati bee bee lo. Awe gbolohun le wa ni   ibeere, aarin tabi ipari gbolohun. Isori meta ni a le pin si. Awon si ni : 1.     ASODORUKO 2.     ASAPEJUWE 3.     ASAPONLE AWE GBOLOHUN ASODORUKO : eyi ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko nipa lilo oro atoka   “PE” Apeere   : ...