EKO ILE
Eko ile ni
eko iwa hihu, iwa rere, iwa to to, iwa to ye ti obi fi nko omo lati kekere.
Ninu ile
kookan ni ile Yoruba, o je asa pe awon obi maa ko awon omo ni eko iwa hihu.
Eyi ni iwa omoluabi, lati kekere ni iwa yii ti n bere ti yoo si di moli fun omo
titi ojo aye re. Eko ile lo bayii
IKINI
LORISIRISI : omode gbodo mo bi a ti ki eniyan paapaa awon ti won ba ju u lo ni
ojo ori ni igbakuugba ti o ba jade lo tabi ti o ba n wole bo. Omode gbodo fi
owo han yala nipa didobale tabi ni ipo ikunle ni asiko ikini. Omode kii duro
gbagidi ki agbalagba ni ile Yoruba. Omode kii beere lowo agbalagba se Alafia
ni, afojudi ni iru iwa bee.
ITOJU ILE
ATI ARA : Awon obi ni lati ko omo pelu lati we ati lati run orin ki won to jeun
ni aaro, ki won si wo asa to dara si ara. Ninu ile onigbagbo tabi musulumi
omode ni lati mo bi a ti n gbaduro ni owuro ati ni ale. Omode tun ni lati maa
ran obi lowo lati sise ile.
IBOWO FUN
AGBA ATI ALEJO SISE : ni akoko ounje, awon obi maa ko omo won bi won se ni lati
jokoo pelu owo ati ipamora bi won ba fe ba agbalagba jeun. Bi won se ni lati we
owo won ati bi won ti ni lati fi ibarale jeun. Omode kii pe agbalagba to ba to
bi ni omo ni oruko. Lati kekere ni a o ti ko omo bi a se n se itoju alejo nipa
fifun alejo ni omi saaju ounje. Bi a se n pon omi si baluwe ati bi a ti n fi
ohun irele beere ohun-kohun lowo won. Won ko gbodo won obi won ni iwokuwo.
IWA OMOLUABI
L: iwa iwora ati oju kokoro ki i se iwa omoluabi, o je pataki lati ko omode pe won ko gbodo saaju agba mu eran ninu ounje , iwa omoluabi ni ki a ran agba
l’eru tabi ki a ran opo lowo tifetife. Omoluabi gbodo mo bi a ti n dupe ore.
Comments
Post a Comment