Skip to main content

ATUNYEWO IRO EDE SSS1(FIRST TERM)



 ATUNYEWO IRO EDE

AKORI ISE: - APEJUWE IRO KONSONANT

Iro – ede: ni ege ti o kere julo ninu enu eyi ti a le fi  eti gbo ninu ede. Awon ni iro konsonanti, iro faweli ati iro ohun.


 IRO KONSONANTI

Konsonanti ni iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti afi gbe won jade. Awon iro konsonanti ede Yoruba niyii


 

Letanla

B  D  F  G   GB  H  J  K  L  M N  P  R   S   S   T   W  Y

 

Leta wewe

 

b  d  g  gb  h  j  k  l  m  n    p   r  s s t   w  y

 

Ipin – sowoo konsonanti.

Ti a ba fe pin konsonanti si owoowo ona meta ti a maa n wo ni wonyii

I.        Ibi isenupe

II.        Ona isenupe

III.        Ipo alafo Tan- an- na

 

 

a)   Ibi isenupe : - ni oga gan ibi ti a fi pe iro konsonanti ni enu, iyen afipe ti a lo (afipe asunsi ni tabi afipe akanmole)  , ati ibi ti won ti pade.

Isori owo Ibi isenupe je mejo Awon ni:-

Afeji- été- pe              Afafasepe

Aferigipe                     Afafasefetepe

Afajape                                   Afitan- an- nape

Afeyinfetepe               Afajaferigipe


IBI ISENUPE

Konsonanti

Isesi Afipe

Afeji- ete- pe

b,m

Ete oke (afipe akanmole ati ete isale Afipe asunsi pade

Afeyifetepe

F

Eté isale (afipe asunsi) ati eyin oke(afipe akanmole)

Aferigipe

t, d, s, n, r

iwaju ahon (afipe, asunsi) sun lo ba erigi oke (afipe akanmole)

Afajaferigipe

J, S

Iwaju ahon (afipeasunsi) sun kan erigi ati aarin aya enu (afipe akanmole)

Afajape

Y

Aarin – ahon (afipe asunsi) sun lo ba aja enu (afipe akanmole)

Afafasape

K, g

Eyin – ahon (afipe asunsi) sun lo kan afase (afise akanmole)

Afafasefetepe

p, gb, w

EEte mejeeji papo pelu eyin ahon (afipeasunsi) kan afase (afipe akanmole) inu alafo tan- an- na ma ti pee

 

ii) ONA ISENUPE : - Ona isenupe ni o n to ka si iru idiwo ti afipe se fun eemi, ipo ti afase wa, ati iru eemi ti a fi gbe kononanti jade isori owo ona isenupe je meji awon ni : Asenupe, Arehon Afunnupe, Afegbeenupe ,  Aranmu ,Aseesetan, Asesi

 

ONA ISENUPE

Konsonanti ti ape

Iru idiwo ti afipe se fun eemi

Asenupe

b, t, d, k, g, p, gb

Konssonanti ti a gbe jade pelu. idiwo ti o po julo fun eemi. Afase gbe soke di kaa imu awon afipe pade lati sse eemi. Ase enu, awon afioe wapo, eemi inu enu ro jade nigba n ti a sii

Afunupe

F, s, s, h

Awon afipe sun mo ara de bi pe ona eemi di  to ore eemi jade pelu ariwo bi igba ti taya n yo jo.

Asesi

J

A se afipe po, eemi to gbarajo ni enu jade yee bi awon afipe sesi sile

Aranmu

m, n

Awon afipe pade ati di ona eemi afase wale, ona imu la. Eemi gba kaa imu jade

Arehon

R

Ahon kako soke ati seyin, abe iwaju ahon fere lu erigi, eemi ko jani ara igori ahon.

 

 

AKORI ISE: - APEJUWE IRO FAWELI

Faweli ni iro ti a pe laisi idiwo kan kan fun eemi

Awon faweli ede yoruba ni wonyii

a          e          I           o          o          u

an        en        in         on        un

IPIN SO WOWO IRO FAWELI

Ti a b a fe pin iro faweli si owo a ni lati ye ona merin wonyi wo

  I.        ipo ti afase wa

II.        Apa kan ara ahon to gbe soke lo ni enu

III.        bi apa toga soke se ga to ni enu

IV.        ipo ti été wa.

IPO TI AFASE WA

Afase legbera soke di ona imu tabi ki o wale ki ona imu lai Eyi lo faa ti a fin ni faweli airamupe ati faweli aranmupe.

a)        FAWELI ARANMUPE: Faweli ti a pe ni gba ti afase gbe soke di ona si imu, ti eemi si gba enu nikan jade. Apeere iro bee ni :

a  e    e    i   o  o   u

b)       FAWELI AIRAMMUPE : -  Faweli ti a pe ni gba ti afase wa sile, ona si imu la, eemi gba kaa inu ati enu jade lekan naa. Apeere faweli bee ni : an, en, in, on, un

IPO AHON

Ti a b ape faweli, apa kan ara ahon maa n gbe si owo, ani lati mo :

a)        APA KAN ARA AHON TO GBE SOKE TU LO NI ENU : - Ibi meta ni ahon ile gbere soke julo ninu enu, eyi ni iwaju, aarin ati eyin. idi niyi ti a fi le pin faweli si owo meta yii.

            I.     FAWELI IWAJU : - Ti a pe ni gba ti iwaju ahon gbe soke ju lo ni enu. Awon ni :- i, e, e, in, en

          II.     FAWELI AARIN : - Faweliti a pe nigba aarin ahon gbe soke ni lo ni nu enu. Awon nii : - a ; an

         III.     FAWELI EYIN : - Faweliti a pe nigba ti eyin ahon gbe soke julo ninu enu. Awon ni: - u, o, o, un, on

b)       APA TO GA SOKE SE GATO NINU ENU: - Eyi ni I won bi ahon se ga to ninu enu. Bi a ba to gbigbe soke ati giga to ahon ni enu bi osuwon, a le pin faweli si ‘’owo’’ yii

            I.     FAWELI OKE / AHANUPE: Faweli ti a pe ni gba ti apa kan ara ahon gbe si oke de aja enu ti aha – enu pee (ahanupe) Awon ni: I, u, un, in

          II.     FAWELI EBAKE /AHANUDIEPE: Faweli ti a pe ni gba ti apa kan to gbe soke ni ara ahon de ebake ti aha- enu- die- pee (ahanudiepa) Awon ni: e, o

         III.     FFAWELI EBADO /AYANUDIEPE: Faweli ti apa kan to gbe soke de ebado ti a ya – enu die pee (ayanudiepe) awon ni: e, o, en, on

FAWELI ODO /AYANUPE: Faweli ti a pe ni gba ti apa kan to gbe si oke ni ara ahon wa ni odo ko to nnkan ti a ya – enu pee (ayanupe) Awon ni: a, an

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)          ...