Skip to main content

ARANGBO (Ewi ti a fi oro inu won damo) JSS2 (FIRST TERM)

 


ARANGBO

O je ewi alohun ti a n fi oro inu won ti a ba gbo da won mo yato si ewi alohun miiran. O pin si isori mefa. Awon ni wonyii :- Alo apamo, oriki, Ese ifa, Owe, Ofo ati Aro.

 

ORIKI :- ni ewi alohun ti a fi n seponle eniyan tabi nnkan miran bii igi, eranko, eye, ounje,orisa ilu ati bee bee lo. Oriki le je eyo oro kan tabi akojopo oro. Apeere , Ayinde, Ayinla, Adisa, Asake,  Omo akaba, Ogidi Olu, Eleyinju ege, Ibadi aran, Aguntasolo.

Awon ohun ti o ma jeyo ninu oriki ni :

1.     ORUKO ILU – Agunmo, omo oye ife

2.     ORUKO IDILE—Omo akaba owo remo

                            Omo adada owo re mo

3.     IRISI TABI ISESI- Laakaye Osinmole

                             O-lo-mi-le-feje we

                              O-laso-nile-fimokimo bora-bi-aso

4.     ITAN KEKERE, ISE, EEWO ati bee bee lo 

ESE IFA ni oriki odu to yo loju opon ifa, ti awon babalawo maa n ki ti won n ba difa. Koko ohun ti ifa maa dale lori ni oye ati eebo riru. Awon oro ti a gbo fi da a mo yato niyi

1.     A dia fun

2.     Ero ipo, Ero ofa

3.     Riru ebo ni gbeni, Airu ebo ki i gbe ni

4.     pawo lekee, O pesu lole,

5.     meeji keta, O lo oko alawo

 OFO : eyi je oro ijinle ti o ni agbara ase ninu. Awon oro inu ihun ofo ti a fi le gbo fi da mo yato niyi

1.     Lilo apola :  A ki i/ kii

2.     Didaruko eroja oogun

3.     Oro iregun /Awijare

4.     Oro ebe, Adura tabi Iwure

5.     Oro ma

ALO APAMO:- eyi  je gbolohun kekere ti awon omode n fi daraya ni ale. O n mu kii omode gbon sasa. Apeere alo apamo ati idahun.

1.     Okun n ho yeeye, Osa n ho yaaya, omo buruku tori bo o. kinni oo ? (omo orogun)

2.     A ni ki o ya orun, oya orun, A ni ki o ya ina, O ya ina, A ni ki o wa we o ni iku de o. kinni oo ( IYO)

3.     Winni winni aso orun, Eni hun un  ko mo-on. Eni to ra a ko mo-on. Kinni oo ( OYUN)

4.     Gbogbo igi lo wowe, Sapata o wowe. Kinni (igi-ope)

5.     Mo sumi barakata. Mo fewe feregede bo o. kini oo. ( ile ati Oju Orun)

OWE:- EYI NI ORISI ewi alohun ti o kun fun oro ijinle ti awon agba maa n lo lati fi salaye oro . o maa n ni itumo lerefee ati itumo kikun. Apeere  

       I.          Obe ti baale ile kii je, iyale ile kii se/ohun ti enikan ba fe naa ni ki a ba fe

    II.          Ogun omode kii sere fun ogun odun /bi o ti wun ki a pep o to, iyapa yoo de lojo kan

  III.          Bi eti o ba gbo yinkin, inu kii baje/iroyin buburu ni ninu je

   IV.          Aguntan to ba aja rin yoo je igbe/ki a sora fun orekere ni bibarin

ARO/IMO: o je okan ninu ere osupa awon omode maa n see lati daraya. O jo alo apamo, ko ni orin sugbon o gba inu

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

AWE GBOLOHUN (JSS)

 AWE GBOLOHUN   AWE GBOLOHUN ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa n se . ona meji Pataki ni awe gbolohun pin si . Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe, Olori awe gbolohun maa n da duro, yoo si ni itumo, o si maa n sise gbolohun abode. Apeere   1) Ola ti sun                2) Mo n bo   Awe gbolohun afarahe tabi afibo : eyi ni gbolohun ti ko le da duro ko si fun wa ni itumo, o maa darale olori gbolohun ni, o si maa n wonpo ninu gbolohun olopo oro ise ( onibo )   Lara awon atoka gbolohun afarahe ni : ti, pe, ki, iba, bi, boya, tabi ati bee bee lo. Awe gbolohun le wa ni   ibeere, aarin tabi ipari gbolohun. Isori meta ni a le pin si. Awon si ni : 1.     ASODORUKO 2.     ASAPEJUWE 3.     ASAPONLE AWE GBOLOHUN ASODORUKO : eyi ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko nipa lilo oro atoka   “PE” Apeere   : ...