Skip to main content

APEJUWE IRO FAWELI. JSS2 (FIRST TERM)

 


ISORI EKO :APEJUWE IRO FAWELI.

Faweli  ni awon iro ti a pe lai si idiwo Kankan fun emi to n bo lati inu edo-foro..

 Ti a ba fe pin iro faweli si owoowo ilana ti a saba ma n wo ni ona merin  wonyi.

1.     Ipo ti afase wa

2.     Apa kan ara ahon to gbe soke julo ninu enu

3.     Bi apa to ga n se ga to ninu enu

4.     Ipo ti ete wa.

IPIN-SOWOO IRO FAWELI

IPO TI AFASE WA                                     

1.     FAWELI AIRANMUPE : faweli ti a  pe nigbati afase gbe soke lati di ona imu , ti eemi si gba enu jade. Awon wonyii ni : a e e I o o u.

2.     FAWELI ARANMUPE : faweli ti a  pe nigba ti afase gbe wa sile, ona imu si la , eemi gba kaa imu jade leekan naa. Awon wonyii ni an, en, in, on, un.

 

      APA KAN AHON TO GBE SOKE JU LO NI ENU

1.     FAWELI IWAJU : faweli ti a pe nigba  ti iwaju ahon gbe soke ju lo ni enu. Awon wonyii ni  : i, e, e, in , en

2.     FAWELI AARIN : faweli ti a pe nigba ti aarin ahon ba gbeko julo ni enu. Awon wonyii ni a, an

3.     FAWELI EYIN : faweli ti a pe nigba ti eyin ahon ba gbe soke julo ni enu. Awon wonyii ni u, o,o, un, on

      BI APA TO GA NAA SE GA TO NINU ENU

1.     FAWELI AHANUPE : faweli ti a pe nigba ti apa ahon gbe soke de aja enu . awon wonyii ni i, u, in, un.

2.     FAWELI AHANUDIEPE :faweli ti a pe nigba ti ara ahon nkan gbe soke ni ara ahon de ibake. Awon ni e, o

3.     FAWELI AYANUDIEPE : faweli ti apa kan o gbe soke de ebado.  Awon ni  e, o, en, on

4.     FAWELI AYANUPE : faweli a pe  ngba ti apa kan to gbe si oke ni ara odo. Awon wonyi ni a, an.

                               

IPO TI ETE WA 

1.     FAWELI PERESE :faweli ti ape nigba ti ete fe seyin , ti alafo gigun tin-in-rin wa laaarin ete mejeeji. Awon wonyi ni : a, e. e. I,an, en, in.

2.     FAWELI ROBOTO : faweli ti agbe jade nigba ti ete ka roboto. Awon wonyii ni o, u, o, un, on

 

APEJUWE IRO FAWELI AIRANMUPE

APEJUWE IRO FAWELI ARANMUPE

/a/ faweli ayanupe aarin perese

/an/ faweli  aranmupe ayanupe aarin perese

/e/faweli ahanudiepe iwaju perese

 

/e/faweli ayanudiepe iwaju perese

/en/faweli aranmupe ayanudiepe iwaju perese

/i/faweli ahanupe iwaju perese

/i/faweli aranmupe ahanupe iwaju perese

/o/faweli ahanudiepe eyin roboto

 

/o/ faweli ayanudiepe eyin roboto.

/o/ faweli aranmupe ayanudiepe eyin roboto.

/u/ faweli ahanupe eyin roboto

/u/ faweli aranmupe ahanupe eyin roboto

 

Comments

Popular posts from this blog

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON EYA ARA - IFO SS1

  AKOLE ISE: ATUYEWO AWON EYA ARA - IFO (EYA ARA ISORO) Eya ara ifo ni eya ara ti a maa n lo fun gbigbe iro ifo jade A le pin eya ara ifo si isori meji, awon ni; Eya ara ifo ti a le fi oju ri: apeere: ete oke, ete isale, eyin oke, e yin isale, evigi, aja enu, iwaju a lo n, aarin lion, eyin ahon, afase, ita gongongo, olele, aja-enu, kaa imu Eya ara ifo ti a ko le fi oju ri: Apeere; Edo-foro, komookun, eka-komookun, tan-an-na, inu gogongo, kaa ofun. AWON EYA ARA TI A FI N PE IRO EDE AFIPE: Afipe ni gbogbo eya ara ifo ti won kopa ninu pipe iro ede jede. A le pin awon afipe wonyi si meji; awon nii APIPE ASUNSI: Eyi ni afipe ti o le gbera nigba ti a aba n pe iro won maa n sun soke sodo ti aban soro. Apeere; Afipe asunsi ni, Ete Isale, Eju isale, iwaju alion, aarin alion, eyin ahon, olele. AFIPE AKANMOLE: Eyi ni awon afipe ti ko le gbara soke sugbon ti won maa n duro gbari bi a ba n pe iro jade. Apeere afipe akonmole ni, ete oke, aja-enu, afase, iganna ofun, eyin oke, erigi, olele. Ipo t...