Skip to main content

AKOTO EDE YORUBA JSS1 ( FIRST TERM )

 

AKORI ISE – BI EDE YORUBA SE DI KIKO SILE

Odun 1842 ni ede Yoruba di kikosile, leyin ti awon eru omo Afirika pada si ile Saro (Sierrialeome) lati Ile Amerika. Aku ni awon oyinbo maa koko pe awon Yoruba ati ede won nitori ikini won to kun fun. E ku ----- E ku.

Bisoobu Samuel Ajayi Crowther ati ijo siemeesi (C.M.S) ni won se ise ati iranwo julo lori bi ede Yoruba se di kiko sile. Awon alawo funfun ti won tun se iranwo fun kiko ede Yoruba ni

J.B Wood

John C. Raban

Ogbeni M.d Avezac

David Hinderer

Henry Venn

Thomas King

Arinri ajo Clapperton

 

1.      Hannah aya kilham (1824 – 1830) o tenu mo iwulo ede abinibi,  o wa akoko ti o rorun fun won ose agbewo si iwo ororun leemeta.

2.      John C. Reban – (1830 – 1832) o se akojopo awon oro ede yoruba si ona meta.

3.      Henry Venn (1841 – 1872) Akowe agba ijo CMS. Ose akoso bi ede Yoruba yoo se di kiko sile.

4.      C.A. Gollmer (1844) o tumo iwe adura owuro Dekalogi, iwe Ihinrere matiu ati ofin mewaa si ede yoruba.

5.      David Hinderer (1844) o tumo iwe iteswaju ero mimo lati Aye yii ti John Boyan ko si ede Yoruba. Oun ati iyawo re Hannah da Ile Ijosin St David ati Ile-iwe sile ni kudeti ni Ibadan.

6.      Henry Iowsend (1848 – 1859) o da Ile iwe sile ni Abeokuta, o te iwe Iroyin akoko, Iwe iroyin fun awon egba ati Yoruba ni ede Yoruba.

7.      A.M. Thomas (1888) o da iwe iroyin eko sile.

8.      Alufaa J. Venal (1891) o da iwe iroyin iwe eko sile.

9.      Ogbeni Bowdish (1891) o ko  onka ‘’ookan de Eewa’’ (1 – 10) ni ede Yoruba.

10.  Bisoobu Ajayi Crowther – Okan ninu awon eru omo Afrika to gba ominira, odun 1809 ni won bii ni ilu osogun ni eti iseyin ni agbegbe oyo. Odun 1825 ni John Roban se itebomi fun ti won so ni Samuel 9/1/1844 o ko iwaasi ni ede Yoruba ni Ile saro. o lo luuku 1.35 o ko bayii o ko bayii Ohung Ohwoh ti aobili nilnoh reh li a omakpe li omoh olorung.

 

AKOTO EDE YORUBA

Akoto ni sipeli tuntun ti a fi n ko ede Yoruba sile. Odun 1974 ni awon igbimo ede Yoruba fi owo si lilo won. Ona ti a fi le mo sipeli tuntun ni won yii.

       i.          Ki a ya aworan oro kookan si okan wa.

      ii.          Ki a maa ran won lenu tabi ko won sile nigba gbogbo.

Ki a maa se akiyesi won bi a ba n kawe.

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)          ...