Skip to main content

ORO ATI GBOLOHUN ONIPON-NA

 

ORO ATI GBOLOHUN ONIPON-NA

 Pon-na ni ki oro, apola tabi gbolohun kan ni ju itumo kan lo. Pon-na yato si oro apola tabi gbolohun ti ko ni itumo kan pato, lara oro-oruko tabi oro-ise ni a ti maa n ri oro onipon-na ninu ede Yoruba. Bi apeere:

Oro-oruko : OYIN – 1. Oruko eniyan 2. Orisii kokoro kan 3. Ohun alaadun ti a n ri lati ara kokoro tabi igi kan.(ireke)

Oro-ise : GBE -1. Ki a ko nnkan nile 2. Ki eniyan ja ole 3. Ki eniyan wa ninu isoro 4. Ibi ti a fi se ibujokoo.

AWON ONA TI ORO ONIPON-NA GBA WAYE

1.      Ilo oro eyo kan laarin gbolohunle so gbolohun bee di onipon-na. bi apeere : Ayo lo pa a : eyi le tumo si  (1) idunu ni o fi fa iku si ori ara re (2) Ayo ni eni ti o fi nnkan lu u ti o fi ku

2.     Ailo amin ohun si ori oro. Bi apeere : IGBA : a le ri awon itumo wonyi : (i) Ogorun-un meji (ii) Asiko (iii) Orisii eso ara igi kan (iv) ohun ti awon obinrin maa lo lati fir u eru

3.     Ti oro ko ba si ni kiko sile, bi o ti dun leti ni a o fi se itumo re.  Bi apeere Bamiji Ojo (i) Pipe oruko eniyan (ii) Bamiji o jo (iii) Ba mi ji Ojo.

4.     Pon-na maa waye ni igba ti oro ba ni ohun kan naa yala ni kiko sile tabi ni pipe lenu. Bi apeere : RA : (i) ki nnkan baje (ii) Ki eniyan sanwo oja

5.     Lilo oro bi akanlo ede. Bi apeere :Baba Ade lawo : (i) Baba Ade ko lahun (akanlo ede) (ii) Baba Ade ya owo re ti a si ri (itumo adamo)

6.     Ti isunki tabi aranmo ba waye ninu apola oro. Bi apeere : Kaso : le tumo si ‘ko aso’ tabi ‘ka aso’. Foko : le tumo si ‘fo eko’ tabi fe oko’

7.      Lilo oro asopo bi ati, ayafi tabi afi. Bi apeere : Folasade feran iresi ati ewa. (a) Folasade feran iresi, o tun feran ewa. (b) Folasade feran lati maa je mejeeji po.

Comments

Popular posts from this blog

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON EYA ARA - IFO SS1

  AKOLE ISE: ATUYEWO AWON EYA ARA - IFO (EYA ARA ISORO) Eya ara ifo ni eya ara ti a maa n lo fun gbigbe iro ifo jade A le pin eya ara ifo si isori meji, awon ni; Eya ara ifo ti a le fi oju ri: apeere: ete oke, ete isale, eyin oke, e yin isale, evigi, aja enu, iwaju a lo n, aarin lion, eyin ahon, afase, ita gongongo, olele, aja-enu, kaa imu Eya ara ifo ti a ko le fi oju ri: Apeere; Edo-foro, komookun, eka-komookun, tan-an-na, inu gogongo, kaa ofun. AWON EYA ARA TI A FI N PE IRO EDE AFIPE: Afipe ni gbogbo eya ara ifo ti won kopa ninu pipe iro ede jede. A le pin awon afipe wonyi si meji; awon nii APIPE ASUNSI: Eyi ni afipe ti o le gbera nigba ti a aba n pe iro won maa n sun soke sodo ti aban soro. Apeere; Afipe asunsi ni, Ete Isale, Eju isale, iwaju alion, aarin alion, eyin ahon, olele. AFIPE AKANMOLE: Eyi ni awon afipe ti ko le gbara soke sugbon ti won maa n duro gbari bi a ba n pe iro jade. Apeere afipe akonmole ni, ete oke, aja-enu, afase, iganna ofun, eyin oke, erigi, olele. Ipo t...