Skip to main content

OYUN NINI. ITOJU ATI OMO JSS3(FIRST TERM)

 


AKORI ISE: - OYUN NINI. ITOJU ATI OMO

Obinrin ti ko bimo ni leyin ojo pipe ni ile oko ni won n pe agan. Awon yoruba ka omo bibi si pupo, won gba pe ko si bi oro eniyan ti le po to ti ko ba bimo, aye asan ni oluwa re wa. Abiku nigba miran le so obinrin di agan.

                                             

Itoju oyun laarin osu kinni si iketa ko le. Obinrin ko gbodo naju. ki oyun re maa baa wale. oko gbodo maa ran an lowo ninu ise ile. leyin osu keta ni oko aboyun yoo to wa onisegun ti yoo maa toju aboyun lati ri pe oyun naa ko baje tabi bi omo ti ko pe ojo.

               Aajo fun aboyun leyin osu keta ni wonyii

1.     OYUN DIDE : -Bi oyun ba di osu meta ni won o ti dee . Ki oyun maa baje lara obinrin ni won se maa n de oyun titi di akoko ti yoo bimo. Osu kesan-an, tabi to ojo b ape ni won yoo to ja oogun na asile, ki aboyun si bimo.


2.     EEWO KIKA FUN ABOYUN : - Awon nnkan ti asa yoruba ko gbe aboyun laaye lati se ni an pe ni eewo. ona lati daabo bo oyun inu ni o bi eewo. Bi apeere

                 I.          Alaboyun ko gbudo sise lile

              II.          Alaboyun ko gbudo rin ninu orun tabi ni oru

            III.          Ko gbodo je igbin, ki om ore maa ba dota

             IV.          Oko aboyun to je ode gbodo sora pipa eranko abami ni akoko ti iyawo re wa ninu oyun.


3.     ASEJE FUN ABOYUN


4.     AGBO WIWE ATI MINU : Onisegun agbebi yoo se orisirisi aseje tabi agbo fun aboyun


5.     OSE AWEBI ATI AGBO ABIWERE : Ti oyun ba ti osu mejo onisegun yoo fun-un ni agbo abiwere, eyi yoo mu ara de.

 

 

ITOJU OYUN TI ODE ONI

Bi obinrin baa ti loyun ni yoo ti lo fi oruko sile ni ile iwisan ijoba ipinle tabi ibile ni agbegbe refun ayewo ati itoju. Alaboyun yoo maa lo si ile iwosan bee loorekoore gege bi adehun tito ti yoo fi bimo.

       I.          Idanilekoo ati ayewo omo inu

    II.          Oogun ati abere

  III.          Ounje afaralokun

 

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

AWE GBOLOHUN (JSS)

 AWE GBOLOHUN   AWE GBOLOHUN ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa n se . ona meji Pataki ni awe gbolohun pin si . Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe, Olori awe gbolohun maa n da duro, yoo si ni itumo, o si maa n sise gbolohun abode. Apeere   1) Ola ti sun                2) Mo n bo   Awe gbolohun afarahe tabi afibo : eyi ni gbolohun ti ko le da duro ko si fun wa ni itumo, o maa darale olori gbolohun ni, o si maa n wonpo ninu gbolohun olopo oro ise ( onibo )   Lara awon atoka gbolohun afarahe ni : ti, pe, ki, iba, bi, boya, tabi ati bee bee lo. Awe gbolohun le wa ni   ibeere, aarin tabi ipari gbolohun. Isori meta ni a le pin si. Awon si ni : 1.     ASODORUKO 2.     ASAPEJUWE 3.     ASAPONLE AWE GBOLOHUN ASODORUKO : eyi ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko nipa lilo oro atoka   “PE” Apeere   : ...