Skip to main content

IGBEYAWO SSS1 (FIRST TERM)

 


KOKO EKO  IGBEYAWO IBILE

 Asa Pataki ni asa igbeyawo  je ni igbesi  aye awon Yoruba, awon irufe igbeyawo aye atijo ni wonyi

1.     FIFE NISU-LOKA

2.     IGBEYAWO ASANTE

3.     IFOMOTORO

4.     IYAWO ORISA

Igbeyawo ibile : Eyi ni igbeyawo  fife nisu loko

IGBESE IGBEYAWO IBILE

1.)   IFOJUSODE : Bi omokunrun ba ti agba, awon obi tabi ebi re re yoo maa fi oju sode lati wa obinrin to dara fun un. Bi oun naa ba si ri eni to wu u, yoo fi to won leti.

2.)   IWADI : Yoo se iwadii idile obinrin naa. ‘obi omokunrin yoo wa alaarina. Iyen eni ti mo awon obi omobinrin naa tiletile. Ise re ni lati wadi boya idile rere ni omobinrin naa ti wa.

3.)   IJEHEN :  Alarina yoo seto bi omokunrin ati omobinrin yoo se ba ara won soro. Bi omokunrin ba ti ba omobinrin soro, ti omobinrin si ti gba , eyi ni Isihun tabi Ijehoo. Omokunrin yoo sanwo isihun. Ise alarina pari.

4.)   ITORO : Obi omokunrin yoo lo toro omobinrin lowo awon molebi re ni owuro kutu.  Baale yoo sure fun omokunrin ati omobinrin ni oruko gbogbo ebi. Ojo yii ni obinrin ti di iyawo afesona. Awon asoju idile mejeji yoo si mu emu ati oti kii won to tuka.

5.)   IDANA : Awon ebi oko yo sanwo idana, idile omokunrin yoo ru eru idana wa . apeere : Ogiju obi ajooopa, Ogoji Orogbo, Ogoji isu, Ataare Mewa  ati bee bee lo. Bi afesona  ba kere lojo ori, omobinrin yoo ma se ana titi omobinrin yoo fi dagba.  Ana-sise le je nipa reran baba iyawo lowo ni ise-oko. Ile kiko, ona yiye, ifowo-ran-ni-lowo. 

6.)   IGBEYAWO : Ayeye ni ile oko ati iyawo, iyawo yoo maa paaro aso. Won yoo maa fun ni ebun, won yoo si maa gbadura fun un pe ile oko yoo san fun owo,fun omo.

7.)   WIWE ESE IYAWO:  Enu ona abawole ni awon obinrin ile yoo ti pade iyawo. Won yoo bu omi si lese. Ami yii nip e o fi ese  ire wole oko. Iyale  iyawo yoo gbe iyawo wo ile. (I-GBE-IYAWO).

8.)   IBALE : Bi oko ba ba iyawo nile, iyen ni pe iyawo yege, ibale ni apeere pe iyawo ko ti I ni ibasepo kan ri pelu okunrin. Oko re yoo paroko ranse si ana re pelu ekun akengbe emu ati owo ibale. Aabo agbe emu ni won yoo fi paroko si obi iyawo ti oko ko ba ba nile.

IGBEYAWO ASANTE: eyi ni igbeyawo ti ko ni ifowosi awon obi ninu. Iru iyawo bayi kii fese mule, tokataya le kora won ni nigbakugba. Igba miran o le je awon obi obinrin ni won yoo ni ki oko ki o wa mu iyawo re ni apapondodo, ti won ba sakiyesi pe iyawo ti won fi wa toro naa n rin irinkurin. Gbigbe re yoo dekun itiju ti o le ko ba ebi ti o ba dede  gbe oyun lati ita.

IFOMODEREE:- awon yoruna naa n fi omo won obinrin tore fun ore tabi ebi ti won ba feran lati le mu ki okun ife aarin ore meji le . Omobinrin bee le ma ni ife si i. Ni iru igbayawo bayii oko le san owo ori ati idana. Igbeyawo bayii wopo laarin awon musulumi, won tile n fi omo se saara fun to wu won.

IGBEYAWO ORISA: Eyi ni obinrin ti orisa gba fun awon aworo tabi abore won fun iyawo. Awon eni orisa bii Abuke, Aro, Afin,Arara. Bi iru awon eniyan bayii  ba je obinrin, awon abore orisa obatala ni won maa n fe won. Nigba miran ti obinrin ba lo sode babalawo fun ayewo, oruko re le han loju opon if ape iyawo orisa ni.

: IGBEYAWO ODE-ONI

 

Igbeyawo ode oni pin si orisii meta. Awon ni

1.     Igbeyawo kootu

2.     Igbeyawo soosi

3.     Igbeyawo Mosalasi

                                          

IGBEYAWO KOOTU : Eyi ni o wopo julo ni ode oni nitori pe ko ni inawwo repete ninu.

ILANA IGBEYAWO KOOTU

 

1.     Iforukosile

2.     Ikede

3.     Igbeyawo ninu yara kootu

 

IGBEYAWO SOOSI : Aarin awon leyin kirisiti ni igbeyawo soosi ti n waye

 

ILANA FUN IGBEYAWO SOOSI

1.     Ifito alufa leti

2.     Igbawe ase ijoba

3.     Ikede

4.     Idanilekoo

5.     Igbeyawo

6.     Igbalejo

 

IGBEYAWO MOSALASI :Aafa ni maa n se igbeyawo ni aarin awon elesin musulumi ni mosalasi tabi ninu ile obi iyawo leyin ti awon ebi ba ti fi ohun sokan pe ki won fera won

ILANA FUN IGBEYAWO MOSALASI

1.     Igbayonda

2.     Owo-ife

3.     Adura

4.     Oro iyanju

5.     Idana

6.     Adura ikaadi

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

ATUNYEWO IPOLOWO OJA SSS2 (FIRST TERM)

  AKORI ISE : IPOLOWO OJA Ki awon eebo to de ni awon Yoruba ti n polowo oja,Ipolowo oja ni kikede ti a n kede oja ti a n ta fun awon eniyan ki won ba le mo ohun ti a n ta. ORISIIRISII ONA IPOLOWO OJA: (1) IPATE:Awon oloja le gbe oja sile ni oja, ikorita   ona oko tabi iwaju ile ni ori eni,tabili,kanta tabi kankere fun tita.Awon eleran osin le so eran won mo ori iso ,Ki aladiye ko adiye sinu ago ni oja lati ta.Eyi ni a n pen i ipate oja (2) IKIRI :Awon oloja maa n ru oja le ori kiri lati ta.Awon nnkan bee yoo je iwonba nnkan ti ko ni wuwo pupo .Awon alate oniworobo maa n kiri oja . (3) OGBON TI A FI N FA ONIBARA LOJU MORA Orisi ete ni awon ontaja maa n lo lati fa awon onibara mora ,ki won le so won di onibara titi kanri. (i)              ENI :Eyi nififi nnkan di si ori nnkan ti onibara ra bi ore.A le fi eni si eko tutu,iresi,gaari,epo abbl (ii)          ...