Skip to main content

IGBEYAWO IBILE JSS1 (FIRST TERM )


 

KOKO EKO  IGBEYAWO IBILE

 Asa Pataki ni asa igbeyawo  je ni igbesi  aye awon Yoruba, awon irufe igbeyawo aye atijo ni wonyi

1.     FIFE NISU-LOKA

Igbeyawo ibile : Eyi ni igbeyawo  fife nisu loko

IGBESE IGBEYAWO IBILE

1.)   IFOJUSODE : Bi omokunrun ba ti agba, awon obi tabi ebi re re yoo maa fi oju sode lati wa obinrin to dara fun un. Bi oun naa ba si ri eni to wu u, yoo fi to won leti.

2.)   IWADI : Yoo se iwadii idile obinrin naa. ‘obi omokunrin yoo wa alaarina. Iyen eni ti mo awon obi omobinrin naa tiletile. Ise re ni lati wadi boya idile rere ni omobinrin naa ti wa.

3.)   IJEHEN :  Alarina yoo seto bi omokunrin ati omobinrin yoo se ba ara won soro. Bi omokunrin ba ti ba omobinrin soro, ti omobinrin si ti gba , eyi ni Isihun tabi Ijehoo. Omokunrin yoo sanwo isihun. Ise alarina pari.

4.)   ITORO : Obi omokunrin yoo lo toro omobinrin lowo awon molebi re ni owuro kutu.  Baale yoo sure fun omokunrin ati omobinrin ni oruko gbogbo ebi. Ojo yii ni obinrin ti di iyawo afesona. Awon asoju idile mejeji yoo si mu emu ati oti kii won to tuka.

5.)   IDANA : Awon ebi oko yo sanwo idana, idile omokunrin yoo ru eru idana wa . apeere : Ogiju obi ajooopa, Ogoji Orogbo, Ogoji isu, Ataare Mewa  ati bee bee lo. Bi afesona  ba kere lojo ori, omobinrin yoo ma se ana titi omobinrin yoo fi dagba.  Ana-sise le je nipa reran baba iyawo lowo ni ise-oko. Ile kiko, ona yiye, ifowo-ran-ni-lowo. 

6.)   IGBEYAWO : Ayeye ni ile oko ati iyawo, iyawo yoo maa paaro aso. Won yoo maa fun ni ebun, won yoo si maa gbadura fun un pe ile oko yoo san fun owo,fun omo.

7.)   WIWE ESE IYAWO:  Enu ona abawole ni awon obinrin ile yoo ti pade iyawo. Won yoo bu omi si lese. Ami yii nip e o fi ese  ire wole oko. Iyale  iyawo yoo gbe iyawo wo ile. (I-GBE-IYAWO).

IBALE : Bi oko ba ba iyawo nile, iyen ni pe iyawo yege, ibale ni apeere pe iyawo ko ti I ni ibasepo kan ri pelu okunrin. Oko re yoo paroko ranse si ana re pelu ekun akengbe emu ati owo ibale. Aabo agbe emu ni won yoo fi paroko si obi iyawo ti oko ko ba ba nile.

Comments

Popular posts from this blog

IHUN ORO/SILEBU JSS2 (SECOND TERM )

        SILEBU ni ege oro ti eemi lee gbe jade ni eekan soso.Silebu tun le je gige oro si wewe.         IHUN ORO: ihun oro ni ki a hun leta konsonanti ati leta faweli inu ede po di oro.      Orisirisi ona ni ihunoro tabi silebu lee gba waye ninu ede yoruba.Bi apeere: 1.Silebu/ihun oro  lee waye gege bi  faweli. O le je faweli airanmupe tabi faweli      aranmupe.b.a:a,e,e,i,o,o,u,an,en,in,on,un. 2.Silebu/ihun oro tun le waye gege bi apapo konsonanti ati faweli. O le je faweli airanmupe tabi aranmupe .Bi apeere : sun,lo, de, gbin, to,ke abbl. 3.Silebu/ihun oro  le waye bii konsonanti aranmu asesilebu.N ATI M.b.a:oronbo,oronro,adebambo.abbl.                                    ...

AWON ORISA ILE YORUBA

ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi.   Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo   Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun   ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi   Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni   Eleri-pin   Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gb...

AWE GBOLOHUN (JSS)

 AWE GBOLOHUN   AWE GBOLOHUN ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa n se . ona meji Pataki ni awe gbolohun pin si . Olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe, Olori awe gbolohun maa n da duro, yoo si ni itumo, o si maa n sise gbolohun abode. Apeere   1) Ola ti sun                2) Mo n bo   Awe gbolohun afarahe tabi afibo : eyi ni gbolohun ti ko le da duro ko si fun wa ni itumo, o maa darale olori gbolohun ni, o si maa n wonpo ninu gbolohun olopo oro ise ( onibo )   Lara awon atoka gbolohun afarahe ni : ti, pe, ki, iba, bi, boya, tabi ati bee bee lo. Awe gbolohun le wa ni   ibeere, aarin tabi ipari gbolohun. Isori meta ni a le pin si. Awon si ni : 1.     ASODORUKO 2.     ASAPEJUWE 3.     ASAPONLE AWE GBOLOHUN ASODORUKO : eyi ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko nipa lilo oro atoka   “PE” Apeere   : ...