ISORI EKO : AWON ORISA ILE YORUBA Awon Yoruba gba awon orisa bii asoju tabi iranse olodumare, alarina, lagata tabi alagbewi ni won je. Ero awon Yoruba ni pe olorun feran awon orisa wonyi. Okanlenirinwo ni awon orisa ile Yoruba . lara won ni Obatala, Orunmila, Esu, Sango, Ogun ati bee bee lo Obatala ni awon Yoruba pe ni ALAMORERE . Won gbagbo pe oun ni o mo gbogbo eya ara eniyan ki olodumare to mi emi iye si inu won Funfun ni awon ohun elo obatala, lara won ni ileke funfun, aso funfun, bata funfun. Ounje ti o feran julo ni obe ate ( obe ti ko ni iyo ), igbin ati iyan. Omi ajipon ni obatala maa n mu. Ko feran iwa aito bi iro pipa ati ole- jija. Ko feran elede, epo, emu, iyo, aja tabi omi ikasi Orunmila ( IFA) ni olodumare fun ni ogbon, imo ati oye lati tun aye se. won gba pe o wa nibe nigba ti olodumare n se ipin ede. Idi niyi ti won fi n pe ni Eleri-pin Sango ti a tun n pe ni OLUFIRAN ti je oba alaafin oyo ri. Won gbagbo pe o ni ogun ati agbara